You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Iléesẹ̀ ọlọ́pàá: NHRC fẹ́ mọ bàwọn afurasí se dé túbú
Àjọ tí ó ń rí sí ẹ̀tọ́ ọmọ ènìyàn (NHRC) yóò ṣe àyẹ̀wò gbogbo túbú àwọn ọlọ́pàá tó wà ní orílẹ̀èdè Naijiríà.
Nínú àtẹ̀jáde kan tí igbákejì agbẹnusọ iléeṣẹ́ ọlọ́pàá, Abayomi Shogunle, gbé jáde lórukọ ọ̀gá ọlọ́pàá ní orílẹ̀èdè Naijiria, Ibrahim Idris ni Ọjọ́rú, ó ní NHRC yóò lọ wo ọ̀nà bí wọ́n ṣe ń ti àwọn ènìyàn mọ́'lé.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
A gbọ́ pé, àwọn túbú àwọn ọlọ́pàá tó ń gbógun ti àwọn adigunjalè (SARS) wà lára àwọn tí wọn yóò wò.
Bí wọ́n ṣe ń ti àwọn ènìyàn mọ'lé ní Naijiria tí jẹ́ ọ̀rọ̀ àfẹnubà fún ọjọ́ tó ti pẹ́. Àwọn kan tilẹ̀ ń kú sínú túbú ọlọ́pàá.
Àwọn ọmọ Naijiria ti wá n fi èrò wọn hàn lórí ọ̀rọ̀ nàá lórí ìkànni Twitter.