Ṣina Peters bú sẹ́kún lórí ikú Ras Kimono, pé ẹni rere lọ

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Gbajúgbajà olórin Reggae ni, Ras Kimono, tí órúkọ rẹ̀ gangan ń jẹ́ Ekeleke Elumelu ti papòdà ní ẹni ọgọ́ta ọdun

Ààrẹ ẹgbẹ́ àwọn olórin ti orílẹ̀-èdè Naijiria (PMAN), Pretty Okafor, ní ikú nàá jẹ́ ìbànújẹ́ ńlá fún àwọn àwùjọ olórin.

A gbọ́ pé ilé ìwòsàn kan ní Ìkòyí ni olórin náà kú sí lẹ́yìn tí ó dákú ní ọjọ́ Àbámẹ́ta.

Ìròyin sọ fún wa pé Ras Kimono ń lọ orílẹ̀-èdè Amẹ́rika kí ó tó dipé ó dá kú, tí wọ́n sì gbée lọ sí ilé ìwòsàn.

Nígbà tí BBC kàn sí olórin Afro-Juju ni, Sir Shina Peters, tí ó jẹ́ ọ̀rẹ́ rẹ̀ tímọ́tímọ́, ṣe ni ó bú sẹ́kún tí kò sì lè sọ̀rọ̀.

Ras Kimono tí ó jẹ́ ọmo Ìpínlẹ̀ Delta ṣe àwo orin rẹ̀ àkọ̀kọ̀ 'Under Pressure' ní ọdún 1989.

A gbọ́ pé Ras Kimono jẹ́ ènìyàn tí kíì mu ọtí. Ó máa ń sọ nínú àwọn ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò pẹ̀lú àwọn akọ̀ròyin pé, "Èmi kìí mu ọtí, sìgá tabi igbó, bẹ́ẹ̀ ni mi kìí ṣe àlágbèrè."

Àwọn ọmọ Naijiria dárò Kimono

Ìkú rẹ̀ di kókó ọ̀rọ̀ tí àwọn ọmọ òrílẹ̀-èdè Naijiria sọ̀ nípa rẹ̀ jù lórí Twitter bi ọ̀pọ̀ ènìyàn ṣe ń ṣe'rántí olóògbé náà pe: