Malawi: Igbákéjì ààrẹ fẹgbẹ́ sílẹ̀ torí àjẹbánu ààrẹ̀

Igbakeji Aarẹ orilẹede Malaw,i Saulos Chilima, ti fi ẹgbẹ oṣelu to n ṣe 'jọba nilẹ naa silẹ, lẹyin igbati o tako Aarẹ orilẹede naa, Peter Mutharika ni gbangba.

Ọgbẹni Chilima ti o tako iwa ajẹbanu labẹ ijọba Aarẹ Mutharika l'ọjọ Iṣẹgun, lo ti kuro ninu ẹgbẹ oṣelu naa.

O ṣeeṣe ki ọgbẹni Chilima dije ninu ibo Aarẹ to n bọ lọna ni orilẹede naa.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Aarẹ Mutharika yan Chilima gẹgẹ bi igbakeji rẹ, ti wọn si jọ dije ninu ibo gbogbo-gboo labẹ ẹgbẹ oṣelu Democratic People's Party ni ọdun 2014.

Ọgbẹni Chilima kede igbesẹ rẹ nitori bi ọpọ eeyan ninu ẹgbẹ oṣelu DPP se ti n rọọ lati dije dupo Aarẹ pẹlu Aarẹ Mutharika, ti o jẹ ọmọ ọdun mọkandinlọgọrin.

Idibo Aarẹ ni orilẹede Malawi yoo waye ni ọdun 2019.