Ọ̀ọ̀ni Ilẹ̀ ifẹ̀ ké s'áwọn adarí láti mójútó àwọn ọ̀dọ́

Bi aarẹ Buhari ṣe n leri leka pe oun yoo buwọlu abadofin to ro awọn ọdọ lagbara lati du ipo oṣelu lorilẹede yii, Ọọni ilẹ ifẹ, kọrọbọtọ bi ọka, jigbini bi akun Ọba Adeyẹye ogunwusi ti ke sawọn adari lati tubọ faaye gba awọn ọdọ ninu eto iṣelu.

Ọọni Ogunwusi pe ipe yii ninu ọrọ to sọ ni aafin ile oodua ni ilẹ ifẹ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

O ni bi awọn onwoye ṣe n sọ ọ wi pe orilẹede Naijiria ti pọ to, awọn ọdọ lo ko ida mẹfa ninu mẹwaa rẹ ti o si jẹ wi pe aifun wọn ni amojuto to peye lee fa ipenija nla fun ọjọ ọla orilẹede Naijiria.

"Awọn ọdọ ni Eledunmare gbe ọjọ iwaju orilẹede Naijiria le lọwọ. Asiko si to fun awọn oloṣelu lati wa wọrọkọ fi ṣada lori ọrọ naa.

Bi a fẹ bi a kọ, ida mẹfa ninu mẹwa awọn ọmọ orilẹede yii ni wọn jẹ ọdọ. Awọn ọdọ lo si ni ilu."

Bakanna ni Ọọni ilẹ ifẹ tun kọminu lori aisi ipolongo to lori eto ifeto sọmọbibi lorilẹede Naijiria.

O ni awọn to wa nipo gbọdọ sapa lati rii pe wọn gbe ipolongo naa de awọn aye gbogbo to yẹ fun awọn eeyan lati ṣe amulo rẹ.