You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ọ̀ọ̀ni Ifẹ̀: Ìbọ̀wọ̀ fún àṣà ni yóò mú Nàìjíríà gòké
Ọ̀ọ̀ni tí Ìlú Ilé Ifẹ̀, Ọba Enitan Ogunwusi, Ojaja kejì, tí ké pe àwọn ọmọ orileede Nàìjíríà láti ṣe igbelárugẹ àti aponle àṣà wá.Ó ní láìsí èyí, ìdàgbàsókè àti igbega kò ní de ba orileede wa.
Ọọ̀ni sọ̀rọ̀ ọ̀hún lásìkò to ṣe abẹwo sí Olú tí Ìlú Warri, Ogiame Ikenwoli ni ààfin rẹ n'ilu Warri nipinle Delta.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Ó ní Eleduwa lo yàn Olú ti ìlú Warri, Ogiame Ikenwoli, fún àwọn ènìyàn Itsekiri àti ìran Yorùbá.Arole Oodua wa kan saara si Olú tí Ìlú Warri fún ọgbọ́n atinuda, ìrẹlẹ ati ojú àánú tó sáfihan bí elédùmarè ṣe ṣeé lọ́jọ tó, gẹ́gẹ́ bí Ọba.Nínú ọ̀rọ̀ rẹ, Olú tí Ìlú Warri tọ́ka sí pé, abewo àkọ́bí Òoduà yóò mú àlàáfíà àti Itesiwaju bá onírúurú ẹ̀yà ni Ìpínlẹ̀ Delta nílé at lẹ́yìn odi.