Ààrẹ Buhari yóò tun tẹko létí lọ London

Ààrẹ Muhammadu Buhari ti orílèèdè Nàìjíríà yóò ṣe ìrìn àjò lọ́jọ́ ìṣẹ́gun sí ìlú London láti lọ rí Dókítà rẹ̀.

Àtẹ̀jáde láti ọ̀dọ̀ olùrànlọ́wọ́ àgbà sì Ààrẹ lórí ìròyìn sọ pé Ààrẹ yóò lo ọjọ́ mẹ́rin tí yóò sì padà sí Nàìjíríà lọ́jọ́ kejìlá oṣù yìí.

Garba Sheu ṣàlàyé pé ''ígbà tí ọkọ̀ bàálù ààrẹ dúró fún àtúnṣe ni London bí ó ti ṣe ń padà láti Washington lààrẹ f'ẹsẹ̀ kan rí Dókítà rẹ. Dókítà rẹ̀ sì ní kó yọjú padà sí òun lẹ́yìn ìgbà náà".

O tẹsíwájú pe ni kété ti Ààrẹ ba darí yóò ṣe àbẹwò sí ìpínlè Jigawa fún ọjọ méjì.

Laarin ọjọ kaarun oṣù kejì sí ọjọ kẹwàá ọdún 2016 lo ṣe àbẹwò àkọkọ.

Èyí tó ṣe kẹyìn wáyé lọjo keje oṣù kaarun ọdún 2017 ti o si darí padà ní ọjọ kokandinlogun oṣù kẹjọ