You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ìfòyà ní Maiduguri bí Boko Haram ṣe ti ya wọ Bárékè
Ìròyìn tó ń tẹ̀ wá lọ́wọ́ láti ìlú Maiduguri ní ìpínlè Bornu ló ń sọ pé àwọn afẹ̀míṣòfò Boko Haram, ti ya wọ bárékè Giwa àwọn ológun ní ìlú náà.
Ọ̀rọ̀ ti di bóòlọ-o-yà-mi, báyìí ní agbègbè tí bárékè náà wà lẹ̀yìn tí àwọn Boko Haram dojú ìjà kọ àwọn ọmọ oogun ilẹ̀ Naijiria.
DSP Edet Okon, to jẹ́ agbẹnusọ fún àwọn ọlọ́pàá, tí ó bá ilé isẹ́ BBC Yoruba sọ̀rọ̀ fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé nkàn kò fara rọ báyìí ní ìlú Maiduguri.
Àwọn ará àdugbò bárékè náà sọ lórì Twitter wí pé àwọn ti ń gbọ́ ìró ìbọn látàárọ̀.
Ó dàbí pé àwọn ọmọ ogun ilẹ̀ ti gbé ìgbésè nítorí ọkọ̀ òfurufú ti ń fò kiri, tí ìró ìbọ̀n sì ti ń dínkù
Àwọn ológun kò tíì sọ̀rọ̀ lórí ìsẹ̀lẹ̀ náà.