Ọ̀ṣun: Iléeṣẹ́ 17 jẹ bílíọ̀nù méjìlá náírà owó orí

Bébà ẹgbẹ̀rún náírà alapapọ

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Àwọn iléeṣẹ́ alaladani méje àti iléeṣẹ́ ìjọba àpapọ̀ mẹ́wàá kan ni aje ọ̀rọ̀ yìí ṣí mọ́ lórí.

Ìjọba ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun ti fún àwọn iléeṣẹ́ tí wọ́n ń jẹẹ́ lówó orí ní gbèdéke ọjọ́ méje làti fi san owó orí tí wọ́n jẹ.

Ìjọba ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun ní òun ti parí gbogbo ìgbésẹ̀ láti gbé àwọn iléeṣẹ́ tọ́rọ̀ náà kàn lọ sílé ẹjọ́ ní kété tí gbèdéke náà bá ti parí.

Olùbádámọ̀ràn lórí ọ̀rọ̀ owó orí sísán nípínlẹ̀ Ọ̀ṣun, Amòfin Gbénga Àkànó ló sọ èyí nilú Ọ̀ṣogbo.

Ó ní àwọn iléeṣẹ́ alaladani méje àti iléeṣẹ́ ìjọba àpapọ̀ mẹ́wàá kan ni aje ọ̀rọ̀ yìí ṣí mọ́ lórí.

Amin iyasọtọ kan

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Amin iyasọtọ kan

Amòfin Àkànó dárukọ àwọn iléeṣẹ́ aladani tó jẹ ijọba lówó orí nípìnlẹ́ náà.

Lára wọn la ti rí ileesẹ́ bíì Glo, 9Mobile, OAU, SAMMYA Nigeria Limited, Wetland Construction Nigeria Limited, LAPO Agric Development Initiative, National Centre for Technology Management, Centre for Energy Research and Development, CERD, Obafemi Awolowo Teaching Hospital àti NTA, Ile-Ife.

Ẹ̀wẹ̀, ó ní àwọn iléeṣẹ́ ìjọba àpapọ̀ bíi iléeṣẹ́ aṣọ́bodè, iléeṣẹ́ ààbò ara ẹni lààbò ìlu, NSCDC, iléeṣẹ́ to ń mójútó wọléwọ̀de lórílẹ̀èdè Nàìjíríà, NIS pẹ̀lú iléeṣẹ́ ọgbà ẹ̀wọ̀n lórílẹ̀èdè Nàìjíríà náà ń jẹẹ́ lówó orí àwọn òṣìsẹ́ rẹ̀ gbogbo.

Lápapọ̀, Olùbádámọ̀ràn lórí ọ̀rọ̀ owó orí sísán nípínlẹ̀ Ọ̀ṣun náà ní, owó tó lé ní bílíọ̀nù méjìlá náírà ni àwọn iléeṣẹ́ tó lórúkọ jẹ ìjọba gégébí owó orí nípínlẹ̀ Ọ̀ṣun.