You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ológun Naijiria: Ènìyàn 28 ló kú nínú ìkọlù Boko Haram
Ilé isẹ́ ológun ti orílẹ̀èdè Naijiria ti sọ wí pé ènìyàn méjìdínlọ́gbọ̀n ló pàdánù ẹ̀mì wọn nínú ìkọlù àwọn ẹsinòkọkú Boko Haram sí agbèègbè ìlà oòrùn Maiduguri, ní ìpínlẹ̀ Borno.
Agbẹnusọ fún Ilé isẹ́ ológun, Ọ̀gágun Onyema Nwachukwu tó tan ìmọ́lẹ̀ sí ìsẹ̀lẹ̀ tó wáyé lọ́jọ́ ìsinmi tó kọjá lọ, sọ wí pé àwọn ọmọogun Naijiria ló kọjú ìjà sí áwọn ẹsinòkọkú náà, tí wọ́n sì dènà àwọn Boko Haram náà láti agbègbè tí àwọn ènìyàn pọ̀ sí.
Ọ̀gágun Nwachukwu sọ wí pé ọmọogun kan, agbésùnmọ̀mí méje àti ẹsinòkọkú mẹ́fà wà lára àwọn méjìdínlọ́gbọ̀n tó pàdánù ẹ̀mí wọn nínú ìsẹ̀lẹ̀ náà.
Òsìsẹ́ àjọ tó ń rísí ọ̀rọ̀ pàjáwìrì ní ìpínlẹ̀ náà sọ wí pé ènìyàn méjìdínláàdọ́rin (68) ló farapa nínú ìsẹ̀lẹ̀ náà, tí wọ́n sì wà ní ilé ìwòsàn tí wọ́n ti ń gba ìtọ́jú.
Tí a kò bá gbàgbé, ìjọba Naijiria sọ wí pé àwọn ń fi omi jomitoro ọ̀rọ̀ pẹ̀lu ikọ̀ Boko Haram láti fòpin sí àwọn ìkọlù tí wọ́n ń se sí agbègbè àríwá orílẹ̀èdé náà.