You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Koko iroyin: Awuyewuye Dapchi, alaboyun tan’gbaloju nibi irọbi
Eyi ni awọn akojọpọ iroyin ti toni.
'Jibiti ni iṣẹlẹ Dapchi, kii ṣe ootọ'
Ni bayi, awọn ọmọbinrin ile-iwe ti awọn Boko Haram tu silẹ ni Dapchi, nipinlẹ Yobe ti wa ni'lu Abuja lati pade Aarẹ Muhammadu Buhari, ṣugbọn ọpọlọpọ ariyanjiyan lo wa lori itusilẹ awọn ọmọbinrin naa.
Ijọba apapọ sọ wipe awọn o san owo kankan lati gba awọn akẹẹkọ naa kuro ni igbekun Boko Haram.
Nigbati ẹgbẹ oṣelu alatako gboogi ni Naijiria, PDP sọ wipe iṣẹlẹ bi wọn se gbe awọn akẹkọ Dapchi itusilẹ wọn mu ifura lọwọ. Ẹ wo ibi fun ẹkunrẹrẹ.
Adajọ paṣẹ $25,000 fun oloyun tan fi'ya jẹ
Ile-ẹjọ kan ni orilẹede Kenya ti da ẹjọ ki ijọba o san iye ẹgbẹrun mẹẹdọgbọn owo ile Amerika, (milionu naira mẹsan) fun obinrin oloyun ti wọn fi iya jẹ ni ile iwosan ijọba lọdun marun sẹyin.
Obinrin naa, Josephine Majani, nigba to n s'ọrọ nile ẹjọ naa ni wipe awọn nọọsi alabẹrẹ gba oun loju niwaju gbogbo awọn eniyan, ti wọn ko si ṣe iranwọ kankan fun oun nigba to n rọbi ni ilẹ nlẹ ile-iwosan naa.
Awọn nkan miran ti ẹ ni lati mọ loni
Gbọ iroyin iṣẹju kan BBC
Fidio wa fun toni
Aṣofin Mamora sọ wipe o yẹ ki wọn ṣe ayẹwo owo ti awọn to n ṣe ijọba n gba latori awọn aṣofin titi to fi de ori awọn adajọ.
Owo oṣu rẹ melo ni wọn ma yọ ninu owo oṣu aṣofin kan lorilẹede Naijiria?
Njẹ o mọ?
Eyi ni pẹtẹẹsi akọkọ (storey building) lorilẹede Naijiria: