Buhari jawọ ninu ilana okoowo tuntun fun Afrika

Aarẹ Buhari n sọrọ.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Igbesẹ yii wa lati fun awọn ti ọrọ kan laaye lati dasi ohun ti Naijiria yoo gbe se lori ilana adehun naa.

Aarẹ orilẹede Naijiria, Muhammadu Buhari ti fagile irinajo rẹ lọ si ilu Kigali tii se olu ilu orilẹede Rwanda fun bibuwọlu eto adehun fun idasilẹ ẹkun karakata ọfẹ laarin orilẹede gbogbo ni ilẹ Afirika (AfCFTA).

Eto bibuwọlu ilana tuntun naa yẹ ko waye ni ọjọ isẹgun, ọjọ kọkanlelogun osu kẹta ọdun 2018.

Igbesẹ yii wa lati fun awọn ti ọrọ kan laaye lati dasi ohun ti Naijiria yoo gbe se lori ilana adehun naa.

Gẹgẹbii atẹjade kan to jẹyọ lati ileesẹ ọrọ okeere lorilẹede Naijiria se sọ, igbesẹ ati wọgile irinajo lati buwọlu adehun naa ko sẹyin bi aarẹ Buhari se n fẹ ki awọn alẹnulọrọ atawọn too niise pẹlu eto ọrọ aje, karakata ati ẹka miran lati da si ọrọ naa nitori aa pe gbọn ni.

Amin iyasọtọ kan

Kini o fa igbesẹ Aarẹ Buhari yii?

Ireti wa wi pe ilana karakata tuntun fun Afirika yii yoo sina ayọ fun eto karakata nilẹ Afirika nipa yiyọ awọn ohun to lee dena jija geerege eto karakata nilẹ Afirika ti yoo si tun fi aaye silẹ fun kiko epo rọbi kaakiri lẹkun naa.

Amọsa awọn ẹgbẹ osisẹ lorilẹede Naijiria ti sọ wipe eyi ko lee so eso rere fun ọrọ aje orilẹede Naijiria ati wi pe yoo fa ọpọlọpọ idaduro lẹnu isẹ.

Pẹlu bi eto idibo apapọ se ku osu diẹ, ohun ti o han gbangba ni wi pe awọn alasẹ ijọba ko ni fẹ iforigbari pẹlu awọn ẹgbẹ osisẹ .