Ijọba ipinlẹ Eko: A ko fi kun owo iwe ọkọ

Ijọba ipinlẹ Eko ti sọ wi pe ko si ohun to jọ ọrọ to nlọ kaakiri pe oun ti fi kun owo ti wọn fi n ṣe iwe ọkọ ati nọmba ọkọ.

Atẹjade kan ti kọmisọna f'eto iroyin nipinlẹ Eko, Kẹhinde Bamigbẹtan ni afọmọ ọrọ yii ṣe pataki pẹlu bi awọn araalu ṣe n beere nipa ahesọ naa.

Bamigbẹtan ni ẹnikẹni to ba ni ẹri pe wọn fi kun owo ti wọn fi n ṣe iwe ọkọ ati nọmba ọkọ, ko wa sọ ọ ni gbangba.

Gẹgẹ bii o ṣe sọ, "lootọ, owo fun atunṣe ọna ati awọn ohun amuludun n gaju ara lọ ṣugbọn ijọba ipinlẹ Eko yoo tubọ maa da ẹru yii gbe lati ri wi pe opona dun un rin fun araalu."

O ni awọn kọlọransi to fẹ lo anfani ipenija to n waye latara ofin owo ori ile ati ilẹ ti ijọba sẹsẹ gbe jade lo n si araalu lọna.

Kọmisọna feto iroyin ni ipinlẹ Eko ni anfani wa fun awọn araalu lati fi kọlọransi oṣiṣẹ yoowu lajọ to n ṣamojuto irinna ọkọ nipinlẹ Eko, MVAA to ba n beere owo lọwọ wọn jofin nipa fifi iroyin nipa irufẹ oṣiṣẹ bẹẹ to ileeṣẹ igbokegbodo ọkọ leti.

Iru awọn iroyin ti ẹ le nifẹ si: