You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Liberia n wa ẹgbẹrun mẹfa tiṣa lati orilẹede Naijiria
Orilẹede Liberia n wa olukọ lati orilẹede Naijiria ti yoo ṣe iranwọ fun orilẹede naa lẹka eto ẹkọ rẹ.
Aarẹ orilẹede Liberia, George Weah ni ẹgbẹrun mẹfa olukọ ni orilẹede oun nilo lati orilẹede Naijiria lati lee kun un lọwọ lẹka eto ẹkọ.
Aarẹ George Weah to wa ni orilẹede Naijiria lati ṣe ipade pẹlu Aarẹ Muhammadu Buhari ni ọjọ aje ni eleyi yoo kun ara adehun iranwọ to wa laarin orilẹede mejeeji.
Lẹyin ipade rẹ pẹlu aarẹ Buhari ni ilu Abuja, Aarẹ George Weah ni orilẹede Naijiria lo lee dide iranwọ fun orilẹede rẹ lori wahala naa.
Amọ ṣa, ibeere ti ọpọ n beere bayii ni wi pe ṣe orilẹede Naijiria lee ri ẹgbẹrun mẹfa olukọ ya orilẹede Liberia bayii pẹlu bii oun pẹlu ṣe n ba awọn iṣoro finra lori eto ẹkọ rẹ pẹlu?
Bi a ko ba gbagbe, laipẹ yii ni ijọba ipinlẹ Kaduna da nkan bii ẹgbẹrun marundinlọgbọn olukọ duro, iroyin eyi to kan kaakiri.
Awọn iroyin ti ẹ le nifẹ si: