Afirika: Awọn aworan awodamiẹnu lọsẹ yi

Eyi ni akojọpọ awọn aworan to jẹ agbayanu nilẹ Afirika ati tawọn ilẹ adulawọ lọsẹ yii.

Oṣere kan ti o n jo ni papakọ-ofuurufu ni Kenya.

Oríṣun àwòrán, AFP

Àkọlé àwòrán, Ni Kenya, awọn oṣere n kopa ninu gbogbo awọn ilana aabo ti o yẹ fun wọn ni papakọ-ofuurufu ti Jomo Kenyatta lati gba ife ẹyẹ idije agbaye FIFA.
Awọn onijo ni Johannesburg lorilẹede South Africa, ni ibi ti wọn n ṣe ayajọ ọdun tuntun orilẹede China.

Oríṣun àwòrán, AFP

Àkọlé àwòrán, Awọn onijo ni Johannesburg lorilẹede South Africa, ni ibi ti wọn gbe n ṣe ayajọ ọdun tuntun orilẹede China.
Ijo kiniun ibilẹ naa tun wa fun afihan bi awọn eniyan ṣe ṣe ayajọ ọdun aja.

Oríṣun àwòrán, AFP

Àkọlé àwòrán, Ijo kiniun ibilẹ naa tun wa fun afihan bi awọn eniyan ṣe ṣe ayajọ ọdun aja.
Ni orilẹede DR Congo, obinrin atipo kan joko ronu nibi ti ogun abẹle ti n da rogbodiyan silẹ.

Oríṣun àwòrán, AFP

Àkọlé àwòrán, Ni orilẹede DR Congo, obinrin atipo kan joko n ronu nibi ti ogun abẹle ti n da rogbodiyan silẹ.
Lẹyin ijinigbe nilu Dapchi, oluyaworan ko firi awọn awọ ti o dara dun un wo.

Oríṣun àwòrán, Reuters

Àkọlé àwòrán, Lẹyin ijinigbe nilu Dapchi, oluyaworan ko firi awọn awọ ti o dara dun un wo.
Ni Jerusalem, lorilẹede Israel, onigbagbọ kan lati Etiopia n gbadura nibi ilẹkun ti ẹnu ọna ṣọọṣi Sepulchure mimọ.

Oríṣun àwòrán, AFP

Àkọlé àwòrán, Ni Jerusalem, lorilẹede Israel, onigbagbọ kan lati Etiopia n gbadura ni ẹnu iloro ṣọọṣi Sepulchure mimọ.
Lẹnu ibode ni orilẹede Egypt. Awọn aworan iponlongo idibo wọnyi ti fihan ni ilu Cairo tii se olu ilu orilẹede n se afihan igbaradi fun eto idibo nibẹ.

Oríṣun àwòrán, Reuters

Àkọlé àwòrán, Lẹnu ibode ni orilẹede Egypt. Awọn aworan iponlongo idibo wọnyi ti fihan ni ilu Cairo tii se olu ilu orilẹede n se afihan igbaradi fun eto idibo nibẹ.
Ọkọ akero miiran, eleyi nilu Nairobi, Kenya ni ibi ti Annastacia Wainaina jẹ ọkan ninu awọn ọmọ ẹgbẹ oṣiṣẹ obinrin ti o ṣiṣẹ ni "matatu" - ọkọ akero apapọ ti ijoba.

Oríṣun àwòrán, AFP

Àkọlé àwòrán, Ọkọ akero miiran, eleyi nilu Nairobi, Kenya pẹlu Annastacia Wainaina jẹ ọkan ninu awọn ọmọ ẹgbẹ oṣiṣẹ obinrin ti o ṣiṣẹ ni "matatu" - ọkọ akero apapọ ti ijoba.
A rekọja okun si Dublin ni Ireland, nibiti ajafẹtọ ara ilu ni Somalia Ifrah Ahmed (lapa alaafia) duro pẹlu Naomi King, ẹniti o nṣere rẹ ninu fiimu tuntun kan nipa igbesi aye rẹ ati ipolongo ati dẹkun didabẹ f'obirin.

Oríṣun àwòrán, PA

Àkọlé àwòrán, A rekọja okun si Dublin ni Ireland, nibiti ajafẹtọ ara ilu ni Somalia Ifrah Ahmed (lapa alaafia) duro pẹlu Naomi King, ẹniti o nṣere rẹ ninu fiimu tuntun kan nipa igbesi aye rẹ ati ipolongo ati dẹkun didabẹ f'obirin.
Lakotan, ẹrin ayọ gba ẹnu ikọ agbabọọlu obinrin orilẹede Ghana nilu Abidjan lẹyin ti wọn f'agba han Ivory Coast lati gba ife ẹyẹ akọkọ wọn ninu idije WAFU - West African Football.

Oríṣun àwòrán, AFP

Àkọlé àwòrán, Lakotan, ẹrin ayọ gba ẹnu ikọ agbabọọlu obinrin orilẹede Ghana nilu Abidjan lẹyin ti wọn f'agba han Ivory Coast lati gba ife ẹyẹ akọkọ wọn ninu idije WAFU - West African Football.

Akojọpọ awọn aworan wọnyii wa lati ileeṣẹ AFP, Reuters, PA ati EPA.