You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ikọlu mẹfa ti o ti waye lawọn ileewe girama lorilẹede Naijiria
Ikọlu alẹ ọjọ aje nibi ti awọn agbebọn ikọ adukukulaja Boko Haram ji awọn ọmọ ileewe kan ko ni ileewe girama Government Girls Secondary School, ni ilu Dapchi, ipinlẹ Yobe kii ṣe akọkọ iru rẹ.
BBC Yoruba ṣe akojọpọ awọn ikọlu to ti waye si awọn ileewe lorilẹede Naijiria laarin asiko ti gulegule awọn ikọ Boko Haram bẹrẹ lorilẹede naa.
Mẹfa ninu wọn ni yi.
Ni oṣu kejila ọdun 2011
Ninu ikọlu kan ti awọn eeyan woye wipe o ṣeeṣe ko jẹ ikọlu lati gba ẹsan oniruuru ikọlu awọn ikọ Boko Haram si awọn ṣọọṣi ni apa ariwa orilẹede Naijiria, awọn eeyan kan ju ado oloro atọwọda si ileewe ẹkọ larubawa kan ni ipinlẹ Delta lasiko ti awọn akẹkọ naa fi n kẹkọ.
Akẹkọ meje lo farapa ninu iṣẹlẹ yii, mẹfa ninu wọn lo jẹ ọmọde ti ọjọ ori wọn ko ju ọdun mẹsan lọ.
Ni oṣu keje ọdun 2013
Awọn agbebọn kan ti awọn eeyan gbagbọ pe wọn wa lara ikọ Boko Haram pa awọn eeyan mejilelogoji, pupọ ninu wọn si jẹ akẹkọ ni ilu Mamudo.
Iṣẹlẹ yii waye lasiko ti awọn agbebọn naa fi kọlu ileewe girama kan ni ipinlẹ Yobe.
Awọn ti iṣẹlẹ naa ṣoju wọn ni n ṣe ni awọn agbebọn naa dana sun awọn eeyan naa laaye.
Ni oṣu keji ọdun 2014
Awọn agbebọn kan ti wọn jẹ ọmọ ikọ Boko Haram dana sun akẹkọ mọkandinlọgọta ni ileewe girama kan ni ilu Buni Yadi nitosi Damaturu tiiṣe olu ilu ipinlẹ Yobe.
Awọn ọlọpa sọọ nigba naa wipe ajodeeru ni awọn eeyan naa jo.
Ni oru ọjọ kẹrinla si ikẹẹdogun oṣu kẹrin ọdun 2014
Awọn agbebọn ikọ Boko Haram kan ji awọn akẹkọ obinrin gbe ni ileewe girama ijọba to wa ni ilu Chibok ipinlẹ Borno.
Bi o tilẹ jẹ wi pe wọn ti ri gba pada lara awọn ọmọobinrin wọnyii, sibẹ awọn kan ṣi wa lahamọ awọn ikọ adukukulaja naa. Kaakiri origun mẹrẹrin agbaye ni awọn eeyan ti bu ẹnu atẹ lu iṣẹlẹ yii eleyi to sọọ di ọkan pataki ninu ohun ti awọn eeyan fi ṣe odinwọn eeyan ti wọn dibo fun lasiko idbo apapọ orilẹede Naijiria lọdun 2015.
Ni oṣu kọkanla ọdun 2014
Ko din ni eeyan mẹrindinlaadọta to ku ti awọn mọkandinlọgọrin miran si fi ara ṣeṣe yanayana nigba ti awọn ọmọ ikọ Boko Haram kan to so ado oloro mọra lọ pa ara rẹ lasiko ti awọn akẹkọ ko ara jọ si ileewe Government Science Secondary School.
Ẹni to so ado iku mọra yii wọ aṣọ ileewe yii lọjọọ naa.
Lẹyin iṣẹlẹ yii ni gomina ipinlẹ naa ti awọn ileewe ijọba gbogbo to wa lagbegbe naa pa.
Ni oṣu karun ọdun 2017
Awọn agbebọn kọlu ileewe girama Government Model College, Igbonla, Epe ni ipinlẹ Eko.
Awọn agbebọn naa ti wọn jọ marundinlogun niye ji akẹkọ mẹfa to jẹ ọkunrin gbe.
Ikọlu ọhun waye ni nkan bii osu meje lẹyin ti awọn agbebọn naa ti kọkọ kọlu ileewe yii kan naa ti wọn si ji igbakeji ọga agba ileewe naa, ati awọn akẹkọ mẹrin.