NNPC n ronu afikun owo epo bentirolu

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Igbimọ ti o ga julọ lori eto ọrọ aje orilẹede (NEC) sọ wipe oun ti bẹrẹ ifọrọjomitoro ọrọ pẹlu ile iṣẹ ajọ elepo rọbi lori afikun owo epo bentirolu lorilẹede Naijiria.
Gomina ti Ipinlẹ Bauchi, Mohammed Abubakar, sọ eyi fun awọn oniroyin lẹyin ipade awọn igbimọ ti o ga julọ lori eto ọrọ aje orilẹede (NEC) pẹlu igbakeji aarẹ Yemi Osinbajo lọjọbọ.
Gomina Abubakar sọ pe igbimọ naa yoo ronu lori owo iye owo epo bentiroolu pẹru irisi awọn orilẹ-ede ti o wa lagbegbe orilẹede Naijiria.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Iye owo epo bentiroolu jẹ ọrọ kan ti o maa n da awuye-wuye silẹ ni orilẹ-ede Naijiria. Ni ọdun 2016, aarẹ Muhammadu Buhari ṣe ẹkun ti o ga julọ si owo epo ti wọn bẹr sii ta epo ni 145 naira. Eyi fa irora fun ọpọlọpọ mẹkunnu.
Ọwọn-gogo epo ti o ruyọ lopin ọdun to kọja ti fa awuyewuye lori boya ijọba apapọ yoo fikun owo epo tabi wọn ko ni se bẹẹ.








