#NigeriaDecides2019: Awọn oloselu Naijiria ati awọn ẹbun ifẹ wọn

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 1

Oriṣii ọbẹ la n ri lọjọ ikú erin ni ọrọ ẹbun awọn oloṣelu lasiko idibo.

Laipẹ yi niroyin gbe wi pe Senator to n soju ẹkun idibo ariwa ipinlẹ Abia, MAO Ohuabunwa pin apẹ idinkara fun awọn eniyan lagbegbe to n soju nileegbimọ asofin agba Naijiria.

Ọgọrọ awọn ọmọ Naijiria ti bu ẹnu atẹ lu igbesẹ naa, bi o ti lẹ jẹ wipe Ohuabunwa ni "oun o kabamọ pinpin apẹ naa" ninu iroyin ti iwe iroyin fi sita.

Kiiṣe Ohuabunwa ni oloselu ti yoo kọkọ pin awọn ẹbun ti a le tọka si bi eyi ti ko bojumu.

Wo awọn oloselu atẹbun arí ṣe haaa!

Gomina Ortum ti Benue naa ko gbẹyin ninu ẹbun rẹ