UAE President Sheikh Khalifa: Ààrẹ ilẹ̀ Arab, Sheik Khalifa ti papòdà ní ẹni ọdún 73

Ààrẹ ilẹ̀ Arab, Sheikh Khalifa ti papòdà ní ẹni ọdún mẹ́tàléláàdọ́rin

Ọkan lara awọn ọba to lọla julọ ni agbaye, Aarẹ Sheikh Khalifa bin Zayed al-Nahyan ti ilẹ United Arab Emirates ti dagbere fun aye.

Ẹni ọdun mẹtalelaadọrin ni Khalifa ko to jade laye.

Mọ sii nipa Sheikh Khalifa

Sheikh Khalifa di Aarẹ orilẹede UAE lati ọdun 2004, amọ ipo ayẹyẹ ni o ma n dimu, ki o to ni aisan rọpa rọsẹ ni ọdun 2014.

Ibatan rẹ, Mohammed bin Zayad al-Nahyan lo n ṣe iṣakoso eto ilu lọwọlọwọ.

Iroyin ni pe o kere tan awọn mọlẹbi ologbe naa yoo ni to aadoje biliọnu dọla owo ilẹ okeere.

Yatọ si aarẹ UAE oun naa ni adari Abu Dhabi to jẹ olu ilu awọn ilẹ meje emirates ti UAE jẹ ọkan lara wọn.

Ileeṣẹ ijọba lorilẹede naa ti kede ogoji ọjọ lati fi ṣedaro akọni to lọ, ti asia orilẹede naa yoo si walẹ fun gbogbo asiko yii.

Bakan naa ni ko ni si iṣẹ ni ẹka ijọba ati aladani fun ọjọ mẹta.

Fun ọdun mẹwaa akọkọ to fi jẹ aarẹ lẹyin baba rẹ to jẹ adari kẹrindinlogun nilẹ naa.

Sheikh Khalifa ni o ṣe atuntọ ni ẹka ijọba apapọ ati ilẹ Abu Dhabi.

Amọ lẹyin aisan rọparọsẹ naa ni awọn eniyan ko ti ri ni gbangban amọ ohun pa aṣẹ.

Ni abẹ ofin ilẹ naa, igbakeji aarẹ, Shekh Mohammed bin Rashid al-Maktoum , ọba ilu Dubai ni yoo jẹ aarẹ fidihẹ fun igba kan naa.

Awọn aṣofin ti ijọba apapọ ilẹ naa yoo ṣepade papọ laaarin ọgbọn ọjọ lati yan aarẹ miran.