Obìnrin kan ń pa ẹgbèrún méjìdínlógójì Pọ́ùn lọ́sẹ̀ fún isó títa

Stephaine Matto nígbà tó ń sọ̀rọ̀ lórí iṣẹ́ àràmàǹdà tó yàn láàyò ẹgbẹ̀rún kan dọ́là ni òun ń ta ìgò isó kan.

Ó ṣàlàyé pé ọ̀pọ̀ ènìyàn tó ń tẹ̀lé òun lórí orí ẹ̀rọ ayélujára fún òun ní àǹfààní láti ní oníbàárà púpọ̀.

Stepahine Matto fi kun pé òun ń ta àádọ́ta ìgò isó lọ́sẹ̀ kan.

Ẹwẹ̀, Stephaine ṣeéṣe kí isó tí ó ti fún kúrò lára pọ̀ púpọ̀ jù bí ó ṣe yẹ lo fi di èrò ilé ìwòsàn.

Ó ní ọ̀pọ̀ ẹ̀wà ni òun jẹ kí òun lè bá à máa rí isó ya ṣùgbọ́n ó ṣe àkóbá fún èèmí òun tí òun rò wí pé òun ti ní síròkì to jẹ arun rọpa rọsẹ.

Dókítà ti ní kí ó pààrọ̀ òunjẹ rẹ̀ báyìí kí àlááfìà le ba Stephaine.

Stephaine Matto ní ohun tí dókítà tí mú òpin bá iṣẹ́ òun ìpinnu tó dùn mọ́ àwọn mọ̀lẹ́bí rẹ̀.