Ilé Ìgbìmọ̀ Aṣòfin orílẹ̀ èdè Kenya dá aṣòfin Fatuma Gedi dúró nítorí súùtì

Ilé Ìgbìmọ̀ Aṣòfin orílẹ̀ èdè Kenya ti dá aṣòfin kan dúró fún ọjọ́ kan fún ẹ̀sún wí pé ó ń pín súùtì lásìkò tí ìjíròrò tó lágbára kan ń lọ lọ́wọ́.

Fatuma Gedi ni wọ́n dá dúró fún ẹ̀sùn wí pé ó ń pín ohun jíjẹ lásìkò tí ìjíròrò ń lọ lọ́wọ́ léyìí tó lòdì sí òfin ilé Ìgbìmọ̀ Aṣòfin náà.

Nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀, Fatuma Gedi ni òun pín súùtì náà láti fi dá okun tí àwọn ọmọ ilé ti pàdánù látàrí ìjíròrò náà padà ni.

Aṣòfin mìíràn, Ndindi Nyoro ni wọ́n tún dá dúró fún ọjọ́ méjì fẹ́sùn wí pé ò parọ́ mọ́ Fatuma Gedi wí pé ó ń pín owó àbẹ̀tẹ́lẹ̀ láì ní ẹ̀rí.

Ẹwẹ̀, Ilé Ìgbìmọ̀ Aṣòfin náà buwọ́lu atúnṣe lọ́kan-ò-jọ̀kan sí òfin tó de àwọn ẹgbẹ́ òṣèlú ṣaájú ètò ìdìbò tó ń bọ̀ lọ́nà ní orílẹ̀ èdè Kenya lọ́dún yìí.