Wo ọ̀nà mẹ́wàá tí o fi lè dábò bo ara ré lásìkò ọyẹ́ yìí

Akoko ọyẹ jẹ akoko kan ti awọn ọmọ Naijiria maa n reti lati oṣu Kọkanla titi di aarin oṣu Kẹta ọdun keji.

Akoko naa jẹ asiko ti atẹgun maa n fẹ lati iha Ariwa ila oorun, tabi lati ila oorun si iwọ oorun Sahara.

Oniruru orilẹ-ede lo ni akoko ti oju ọjọ wọn maa n yipada, fun apẹrẹ, lawọn agbegbe kan Yuroopu, yinyin maa n jabọ lati oju ofurufu.

Ni Naijiria ẹwẹ, a ni igba ojo, a si tun ni igba ẹrun.

Igba ojo maa n bẹrẹ lati inu oṣu Kẹrin ọdun si oṣu Kẹwaa, nigba ti akoo ẹrun maa n bẹrẹ inu oṣu Kọkanla si oṣu Kẹta.

Wo awọn ohun ti o le ṣe lati koju akoko ọyẹ yii;

  • Maa mu omi ni gbogbo igba
  • Maa wọ awọn aṣọ ti yoo daabo bo ara rẹ lọwọ otutu
  • O le maa lo oogun "Vitami C" ni gbogbo igba lọna ati maa fun ara rẹ lokun
  • Lo awọn ipara ti yoo jẹ ki ara rẹ maa jọlọ
  • Ṣora fun ina
  • Ṣora fun awọn agbege ti eruku pọ si
  • Ṣe irun ti yoo dabo bo ori rẹ
  • Maa fi omi fọ oju rẹ loorekoore ki oju rẹ ma ba maa pọn
  • Lo ikunra si ete rẹ ki ete naa ma baa gbẹ
  • Maa jẹ ọpọ esọ lọna ati ṣe ara rẹ loore