You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Baba Ijesha: Onímọ̀ nípa ìhùwàsí ọmọdé mú ẹ̀rí tuntun wá sí iléẹjọ́ lórí ọ̀rọ̀ Baba Ijesha
Igbẹjọ Baba Ijesha tun tẹsiwaju nílé ẹjọ gíga to n gbọ ẹsun ifipabanilopo niluu Eko.
Ṣaaju ni agbẹjọro fún ìjọba ti kọkọ mu ẹlẹri kan, to jẹ onimọ nipa ihuwasi ọmọde, wa siwaju adájọ Oluwatoyin Taiwo to n gbọ ẹjọ náà.
Ẹlẹri náà, Bisi Àjàyí Kayode sọ níwájú ilé ẹjọ ọhun pé ọmọ tí ọrọ naa kan sọ fún oun lásìkò ifọrọwerọ pe lootọ ni Baba Ijesha fọwọ kan òun nígbà tí òun wa ni ọmọ ọdún méje.
- Ṣé lóòtọ́ ni Sunday Igboho ń gbowó ìgbésùnmọ̀mí lọ́wọ́ agbódegbà Boko Haram kan gẹ́gẹ́ bí Malami ṣe sọ?
- Òṣèré Tíátà ṣèèṣì yìnbọn lórí ìtàgé, arábìnrin kan ti forí la ikú, òmìí farapa
- Wo bí wọ́n ṣe yọ́lẹ̀ gbé Nnamdi Kanu wọ inú ilé ẹjọ́ l'Abuja
- Wo ohun tí Baba Ijesha sọ fún BBC níbi ìgbẹ́jọ́ rẹ̀
- Ìjọba ní kí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí ni ṣe àyẹ̀wò ọpọlọ f'áwọn Ọlọ́pàá àti agbófinró
- Wo bí Ooni ti Ile-Ife, Pásítọ̀ Sam Adeyemi, Woli Agba, Falz, Mr Macaroni, Tiwa Savage ṣe ṣe àyájọ́ Endsars!
- Mọ̀ nípa àwọn ọmọ Naijiria tó fẹ́ kí Ísírẹ́lì tẹ́wọ́ gbà wọ́n gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yà Júù
- Wo ohun tí Baba Ijesha sọ fún BBC níbi ìgbẹ́jọ́ rẹ̀
- Wo àwọn gbajúmọ̀ míràn yàtọ̀ sí Tiwa Savage tí ọ̀rọ̀ fídíò ìbálòpọ̀ wọn ti bọ́ sí orí ayélujára ...
Bisi Ajayi tun ṣàfihàn fidio kan níwájú ilé ẹjọ náà, nibi ti oun ati ọmọ náà ti n sọ ọrọ ọhun.
Bó tilẹ jẹ pe agbẹjọro Baba Ijesha gbìyànjú láti da ẹrí Bisi Àjàyí nu lori pe ko koju oṣuwọn lati fi ọrọ wa ọmọ náà lẹnu wò, ṣugbọn adájọ Oluwatoyin Taiwo gba ẹrí náà wọlé.
Wayi ọ, agbẹjọro ìjọba tun ti mu ẹlẹri miran wa siwaju ile ẹjọ náà.
Ẹlẹri tuntun yii, dokita Makanjuola sọ níwájú ilé ẹjọ náà pé òun lo ṣe ayẹwo ọmọ ti ọrọ kan lati mọ boya lootọ ni Baba Ijesha ti fọwọ kan ri.
- "Free Sunday Igboho" lariwo tó gbóde bí àwọn alátìlẹ́yìn rẹ̀ ṣe darapọ̀ mọ́ ìwọ́de ENDSARS ní Ibadan
- EndSARS: Atúpalẹ́ rèé lórí ìkọlù tó wáyé ní Lekki Toll Gate lọ́jọ́ 20 Oct, 2020
- Sanwo-Olu ti gba àwòrán rẹ̀ lọ́wọ́ Boda Taiye Oniyakuya
- Àlàyé rèé lórí ohun tó ń fa ẹ̀kúnwó gegele lórí owó orí afẹ́fẹ́ ìdáná gáàsì
- Ọmọ ilé ẹ̀kọ́ UI méjì fórí kó ọta ìbọn lọ́jọ́ kan ṣoṣo, wọ́n pàdánù ẹ̀mí wọn láàrin wákàtí mẹ́rìnlélógún
- ₦500 tí màá fi ra 'Data' láti fí ṣé Yahoo-yahoo ló mú mí yín ọlọ́kadà lọrùn pa
Nibi ti ọrọ naa de duro báyìí, adajọ ti wa sun ẹjọ náà sì ọjọ karun un ati ọjọ kẹjọ, oṣù Kọkànlá, ọdún 2021 yìí, gẹgẹ bíi oun ti agbẹjọro Baba Ijesha sọ.
Nínú ìfọrọwánilẹnuwò pẹlu BBC Yorùbá, ọkan lára àwọn agbẹjọro Baba Ijesha, ti Babatunde Ogele n dari wọn sọ pé àwọn ṣi n retí ki ìkọ olupẹjọ mú ẹlẹri mẹta mii wa ko to kan awọn.