You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
R. Kelly jẹ̀bi ẹsùn fífi ipá bá ọmọdé ní ìbálòpọ̀ - Ilé ẹjọ́
Ile ẹjọ ti da gbajugbaja akọrin Amẹrika ni, R. Kelly lẹbi lori ẹsun pe o n ṣe agbatẹru lilo awọn obinrin ati ọmọde fun owo nọbi ati ibalopọ ti ko lẹtọ.
Wọn ni o le ni ogun ọdun to ti n wu iwa yi.
Eeyan mọkanla lo fẹsun kan an, ninu wọn ni obinrin mẹsan ati ọkunrin meji ti wọn kopa ninu igbẹjọ ọlọsẹ mẹfa gbako.
Lasiko igbẹjọ yi, wọn ṣalaye fun ile ẹjọ iriri bi olujẹjọ naa ti ṣe fipa ba awọn eyan lopọ to si tun tabuku wọn.
- Mo sún ìgbẹ́jọ́ yìí láàrin Princess àti Baba Ijesha síwájú di 21/10/2021 torípé ...- Adájọ́
- 'Kàǹkàn ìbílẹ̀, òògùn, àwọ̀tẹ́lẹ̀ àti fóònù lá bá lẹ́gbẹ̀ẹ́ òkú obìnrin tí wọ́n dédé jù sí àdúgbò wa l'Akure'
- Ẹ̀yin gómìnà Ariwa, ẹ dá a padà! Ààrẹ Naijiria gbọ́dọ̀ wá láti Gúsù ní 2023 - Afenifere
- Ṣé o tí gbọ́ nípa eNaira, owó àìrí tuntun tí CBN ṣe ìfilọ́lẹ̀ rẹ̀? Nkan tí ó ní láti mọ̀ rèé
- Àwọn ajínígbé ṣ'oró l'Eko, wọ́n jí Ọ̀gágun ojú òfurufú Sikiru Smith gbé
Lẹyin ọjọ meji ti wọn ṣe agbeyẹwo gbogbo ẹri to wa nilẹ, ile ẹjọ da R. Kelly lẹbi lori gbogbo ẹsun ti wọn fi kan an.
R. Kelly yi iwe ọjọ ori Aaliyah ko ba le rii fẹ - Agbẹjọro
Awọn agbẹjọro ijọba sọ pe R Kelly ti orukọ rẹ gangan n jẹ Robert Sylvester Kelly lo okiki ati ipo rẹ lati tan awọn to ko si ọwọ rẹ
Wọn ni o parọ fun wọn pe oun yoo ran wọn lọwọ nidi iṣẹ orin ki o le bawọn ni ibalopọ.
Ọpọ awọn to ko si lọwọ sọ pe awọn ko tii toju bọ nigba to fi ni ibalopọ pẹlu awọn.
Bẹẹ naa ni wọn ni o tapa si ofin kan ti wọn pe ni Mann Act eleyii to lodi si fifi eeyan ṣe owo nọbi laarin ipinlẹ kan si omiran.
Awọn akọroyin sọ pe niṣe ni R. Kelly kan joko to n wo sun nile ẹjọ nigba ti adajọ gbe idajọ rẹ kalẹ ni.
Wọn ko le sọ boju rẹ ti se ri nitori o wọ ibomu ti adajọ ni ki wọn wọ nitori ajakalẹ Covid-19.
Idajọ yi n waye lẹyin ọkan to waye lọdun mẹtala sẹyin ni ipinlẹ Illinois nibi ti wọn ti tu silẹ pe ko mọ si ẹsun biba ọmọde ni ibalopọ
Pupọ ninu awọn ẹsun ti wọn pada waa fi kan yii jẹyọ lẹyin ti wọn gbe fiimu kan jade ti akọle rẹ n jẹ "Surviving R. Kelly."