AAUA students penis dog bite: Ajá kan tí wọn n pe ní Charlie ni ìròyìn ni pé ó gé akẹkọọ Fasiti Adekunle Ajasin ni Akungba Akoko kan ní abẹ jẹ

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 1

Ajá gé ǹkan ọmọkùnrin akẹkọọ AAUA ní Akungba jẹ ní àwọn agbófinró bá mú ajá náà

Aja naa ni wọn ni eya Boerboel ni ti won fun ni orukọ Charlie lo sọ akẹkọọ Fasiti Adekunle Ajasin to wa ni Akungba Akoko naa di èrò ilé ìwòsàn báyii.

Iroyin to gba oju ayelujara kan ni eyi ti wọn n sọ nipa akekọọ okunrin kan ti aja ge ni nkan omokunrin je.

Akekọọ yii ni wọn ni o deede n rin la loju popo nitosi ileegbe awon akekọọ ni Fasiti Adekunle Ajasin to wa ni Akungba Akoko ni ipinle Ondo

Iroyin ni saa deede ni aja kan ti wan n pe oruka rẹ ni Charlie deede bu nkan ọmokunrin akẹkọọ yii jẹ.

Okan lara awon ileese iroyin ayelujara to gbe e sá pe,owo olopaa ti te aja naa bayii

Eyi lo mu ki awọn ọlọpaa mu aja naa satimole de olowo rẹ

Won ni akẹkọọkunrin yii ti n gba itọju nile iwosan bi o ti yẹ