Ibeju Lekki Free Trade Zone: A ti bí ọmọ tó lọ Fásitì tí kò rí iná ọba rí- Olawale Eleto

O yẹ ki ijọba ipinlẹ Eko dọwọ boju ni lori ọrọ ina mọnamọna ni Ibeju Lekki Free Trade Zone- Olawale Eleto

Awọn olugbe Ibeju Lekki ni ipinlẹ Eko ni guusu iwọ oorun Naijiria ti ke gbajare sita lori ọrọ aini ina mọnamọna lati ọdun mẹwaa si ogun ọdun ni awọn agbegbe to le ni ogoji nibẹ.

Agbegbe Ibeju Lekki yi ni ijọba ipinlẹ Eko gbe Free Trade Zone area si ni eyi ti awọn onile iṣẹ nlanla nilẹ yii ati loke okun wa fi ṣe ibujoko si.

Baale Okunraye Ibeju Lekki, Ibrahim Adedeji ba BBC sọrọ lori ipenija ninu ọrọ aje, nipa ilera ati ọpọlọ awọn olugbe agbegbe to le ni ogoji ni Ibeju Lekki yii.

O ni nkan ibanujẹ ni pe wọn ko janfani ijọba awa ara wa nibẹ.Baale Adedeji to n funra rẹ fa ẹrọ amunawa mẹnuba ọpọ ileri awọn oloṣelu lasiko idibo.

Baalẹ ni ọrọ wọn dabi ẹni to fẹ gbawin ẹba ni.

O tun mẹnuba awọn igbesẹ ti awọn ara ilu ti gbe ṣugbọn ti gbogbo rẹ n ja si pabo.

Wakilat Olufowobi to jẹ ọkan lara olugbe Ibeju Lekki royin gbese ti ọpọ oniṣowo ti jẹ nitori airina fi sise nibẹ.

O mẹnuba die lara igbesẹ ti wọn ti gbe to ja si pabo.

Toliatu Eleto to jẹ agba lara a\won to n gbe agbegbe yii naa sọ eyi to ṣoju rẹ nipa bi nkan ṣe ri nibẹ.

O sọ pe ko kọja agbara ijọba lati pa awọn eeyan agbegbe ogoji yii lẹrin.

Nigba ti BBC kan si Komisonna Gbenga Omotoso to wa fun ifitonileti ati eto iroyin ni ipinlẹ Eko, o sọrọ ilẹ kun.

Komisonna naa ṣalaye nipa awọn igbesẹ ti ijọba ipinlẹ Eko ti gbe.

Bakan naa ni Komiṣọnna Omotoso tun sọ nipa ipenija to n koju ijọba ipinlẹ Eko lori wiwa ojutu si iṣoro ina ni ogoji agbegbe to le yii.

O salaye ibi ti iṣẹ de duro pelu ireti pe laipẹ awọn eeyan Ibeju Lekki yoo tan ina Oba.