Barry Jhay's latest news: Èmi náà rí fídíò tó fi síta tí ẹnu rẹ̀ ti ń ṣẹ̀jẹ̀ kò tó di pé ọ

Olaronke Balogun to jẹ ẹgbọn fun Barry Jhay ni awọn ṣi wa lori ọrọ yii torinaa iwọnba ni ẹbi le sọ nipa rẹ.

"Mi o si nibẹ ṣugbọn ọmọ to da a ni aburo mi, o ni iwa to daa, ko si ni ọwọ ninu iku naa".

Olaronke ni awọn gbọ wipe oloogbe Kashy ti ni awọn iṣoro kọọkan to n koju ṣaaju ọjọ iku rẹ.

Koko ọrọ to tẹnumọ ni wipe idile Barrister nigbagbọ ninu ọmọ tiwọn, awọn o lodi si ohun ti idile oloogbe Kashy n ṣe amọ sibẹ sibẹ awọ́n ni lati gbe igbesẹ toripe Barry Jhay ko jẹbi rara.