Unilorin: Ẹ wo ohun tí Fásitì Ilorin sọ nípa Omotanwa tó fí "yẹrín etí" sí imú

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Awọn alaṣẹ fasiti Ilorin ti fesi si iroyin to n ja ranyin lori ayelujara pe awọn ẹsọ alaabo ti fi panpẹ mu akẹkọbinrin to fi yẹti si imu rẹ.

Iroyin ni awọn eleto aabo fasiti naa lo mu arabinrin akẹkọọ naa nitori o wọ yẹti si imu rẹ, to si da irun ori rẹ silẹ, to n wọ ọ ni ara.

Adari eto ilana ileẹkọ Fasiti Ilorin, Kunle Akogun ni lootọ ni awọn gbe igbeṣẹ naa nitori ọmọbinrin akẹkọọ to wa ni ipele Ikini ni fasiti naa tapa si ofin to de ihuwasi ati imura ni ileewe naa.

Arakunrin Akogun ni ikọ to n ṣewadii iwa aitọ awọn akẹkọọ ni yoo fẹju toto si ẹsun ti wọn fi kan arabinrin naa.

Arabinrin ti orukọ rẹ lori Twitter n jẹ 'Omotanwa' lo fi fidio ati fọto lede nibi to ti safihan bi awọn ẹsọ alaabo ṣe yọ yẹti ti oun fi si imu, ti oun si wa ni gbagede awọn ẹsọ alaabo ileewe naa.

Were to fi si ori ẹrọ ayelujara ni awọn eniyan bẹrẹ si ni bu ẹnu atẹ lu igbeṣẹ awọn ẹsọ alaabo fasiti naa nitori wọn tẹ ẹtọ rẹ mọlẹ.

Amọ, ileewe fasiti naa ni awọn ilana ti wọn n tẹle lori imura awọn akẹkọọ ninu ileewe naa.

Bi awọn akẹkọọ ọkunrin ṣe le mura niyii

•Irun wọn gbọdọ wa ni gige , ti o si wa ni yiya ni gbogbo igba

•Wọn ko gbọdọ fi 'colour' si iru wọn, afi to ba jẹ awọ ti iru naa bawa.

•Iru gige wọn ko gbọdọ kọja keremi

•Wọn ko gbọdọ fi ọṣẹ si irun wọn

•Ko si aye fun ki ọkunrin ṣe iru bii dada,tabi ki o di irun rẹ.

•Irun agbọn gbọdọ mọ ni iwọnba, ko si wuni.

Bi imura awọn obinrin ṣe gbọdọ ri niyii

•Awọn akẹkọbinrin le di irun wọn, ṣe ni ọsọ tabi lo 'wig'

•Wọn ko le lo 'colour'orisirisi si irun wọn

•Awọn akẹkọbinrin gbọdọ ko irun wọn jọ ti wọn ba di i

•Gbogbo aṣọ ti wọn ba wọ, gbọdọ kọja orunkun wọn

•Wọn le wọ 'pencil trouser' amọ aṣọ ti wọn ba wọ si ori rẹ gbọdọ bo idi wọn.

•Wọn le wọ aṣọ ibilẹ ti ko ba ti ṣi ara wọn sita.

Awọn imura to jẹ eewọ fun awọn akẹkọọ ni

•Aṣọ to ba ṣi ara silẹ, ṣi igba aya wọn, ọmu, idodo, abiya, ti ko lapa, tabi apa kekere

•'Jeans' to ba fun mọ ara ju, aṣọ ti eniyan le ri ihoho rẹ ninu,

•Ko gbọdọ ṣi tattoo lara wọn, kikun oju gbọdọ jẹ iwọnba

•Wọn ko gbọdọ fi yẹti si imu

•Aṣọ penpe ko wọ fasiti oun

•Ko gbọdọ si pe a n wọ bata baluwẹ wa si ileẹkọ

•Akẹkọkunrin ko le lo yẹti

Awọn alaṣẹ fasiti naa ni idi ti awọn fi fi awọn ilana imura ati ihuwasi naa sita ni lati ri pe awọn akẹkọọ to jade ni fasiti awọn jẹ ọmọluwabi to n mu iwuri ba obi ati awujọ.