Malaysia Church: Ilé Ẹjọ́ fìdájọ́ lélẹ̀, Krìstẹ́nì lẹ́tọ̀ọ́ gẹ́gẹ́ bí àwọn Mùsùlùmí láti pe Ọlọ́run ní Allah

Ile ẹjọ giga lorileede Malaysia ti fofin si ofin ọlọdun marundinlogoji kan to ni awọn Kristeni ko le pe Ọlọrun ni Allah ninu ijọsin wọn.

Ọrọ ki awọn Kristeni maa lo Allah lati juwe Ọlọrun jẹ eleyi to n da wahala silẹ laarin awọn ẹlẹsin mejeeji yi.

Awọn musulumi lo ko ida meji ninu ida mẹta eeyan ilẹ naa ṣugbọn awọn Kristẹni naa wa nibẹ.

Ohun tawọn Kristẹni ilẹ yi n sọ ni pe o ti pẹ tawọn ti n lo Allah lati inu ede larubawa tawọn ti ya si Malay tawọn n sọ.

Gẹgẹ bi wọn se ṣalaye, bi igba ti wọn tapa si ẹtọ awọn ni aṣẹ ma juwe Ọlọrun pẹlu Allah yi jẹ fawọn.

Ofin ilẹ Malysia faaye gba ki onikaluku maa ṣẹṣin rẹ bo ti ṣe wu u ṣugbọn ọrọ orukọ Allah yi jẹ nkan ti awọn eeyan ko dunnu si.

Ko bofin mu ko si tọna

Lọdun 2008 iṣẹlẹ kan waye lori ọrọ yii nigba tawọn alaṣẹ Malaysia fipa gba awọn disiki oniwaasu Kristẹni kan Jill Ireland Lawrence Bill fẹ gbe wọ ilẹ naa.

Idi ti wọn lawọn ṣe bẹẹ ni pe wọn lo Allah lati fi juwe Ọlọrun ninu akọle wọn.

Lati igba naa ni o ti ko ṣẹjọ lati tako ofin ti wọn ti gbe kalẹ lati 1986 pe Kristẹni ko gbodọ pe Ọlọrun ni Allah.

Lọjọru ni ile ẹjọ giga to w ani Kuala Lumpur gbe idajọ silẹ pe idẹyẹsi ni wọn ṣe si latari ẹsin rẹ.

Adajọ Nor Bee sọ pe Allah ati awọn ọrọ mẹta mii Kaabah(ile tawọn musulmi n kọju si kirun) Baitullah to tumọ si ile Ọlọrun ati Solat, irun kiki ti di ẹtọ fawọn Kristẹnilati lo

O ni aṣẹ to ni ki wn maa lo awọn ọrọ yi ko bofin mu.

Igba akọkọ kọ yi ti edeaiyede ti n waye lori lilo orukọ Allah fi juwe Ọlọrun fawọn Kristẹni.