Seyi Makinde fẹ ṣanwó màálù tí wọ́n pa àti owó ìtọ́jú àwọn tó farapa

Iroyin to gbalẹ kan ni pe awọn agbebọn yawọ adugbo kan n'Ibadan, wọn kọlu maalu, bẹẹ si ni awọn eeyan kan fi ara pa.

Amọ ni kete ti awọn eeyan ri igbesẹ ti ijọba ipinlẹ Oyo pinu lati gbe lori rẹ ni wọn bẹrẹ si ni sọrọ lori ayelujara.

Oniruuru ni iwoye awọn eniyan lori iwadii ati igbesẹ ọtun ti gomina fẹ gbe.

L'ọjọ Abamẹta ni awọn agbebọn kan yawọ awujọ Alafara to n bẹ ni agbegbe Ologunẹru n'Ibadan, ti wọn si ṣekupa awọn maalu melo kan.

Iroyin fi idi rẹ mulẹ wi pe awọn eeyan kan naa tun fi ara pa nibi iṣẹlẹ ọhun.

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ ati ijọba ipinlẹ Ọyọ ti fi ọrọ lede wi pe lootọ ni ikọlu naa waye, ninu eleyii ti wọn ti fi ibọn pa awọn maalu kan.

Ninu atẹjade kan ti wọn fi lede lati ọwọ alukoro ajọ ọlọpaa nipinlẹ Ọyọ, Arakunrin Olugbenga Fadeyi, ṣe alaye wi pe lọgan ti Kọmisana ajọ ọlọpaa nipinlẹ Ọyọ, Ngozi Onadeko gbo iroyin nipa iṣẹlẹ naa ni o fi awọn ọlọpaa ṣọwọ si agbegbe naa lati ṣe ofintoto ohun to ṣẹlẹ.

Bakan naa ni ileeṣẹ ọlọpaa ṣe alaye wi pe iṣẹ iwadii ti bẹrẹ lori iṣẹlẹ naa pẹlu igbiyanju lati ṣawari awọn agbebọn to ṣiṣẹ laabi naa.

Ninu atẹjade naa ni Kọmisana ọlọpaa ti ṣe alaye siwaju si i wi pe "ikọlu naa ko ni ohunkohun ṣe pẹlu ija laarin Yoruba ati Fulani" gẹgẹ bi o ṣe parọwa si gbogbo eeyan ipinlẹ Ọyọ lati yago fun gbọyisọyi ti o ni ọwọ ẹlẹyamẹya ninu, ki ẹnikẹni ma si gbe igbẹsẹ ti o le da omi alafia ilu ru.

Kọmisana ajọ ọlọpaa fi kun ọrọ rẹ pe ajọ naa yoo tẹsiwaju ninu ojuṣe rẹ lati maa daabo bo ẹmi ati dukiya awọn olugbe ipinlẹ naa.

Nibayii, Gomina Ṣeyi Makinde ti paṣẹ fun ẹka ileeṣẹ ijọba to n ri si eto ilera lati gbọ gbogbo bukata itọju awọn eeyan to fi ara pa nibi ikọlu naa.

Ninu atẹjade ti wọn fi ranṣẹ si awọn oniroyin lati ọwọ akọwe iroyin fun Gomina ipinlẹ Ọyọ, Taiwo Adisa, Makinde ṣe alaye wi pe awọn aṣoju ijọba ti oluranlọwọ pataki fun Gomina lori eto aabo, Sunday Odukoya le iwaju wọn ti ṣe abẹwo si ibi ti iṣẹlẹ naa ti waye.

Bakan naa ni atẹjade naa tọka rẹ wi pe Gomina Ṣeyi Makinde yoo fun awọn eeyan to padanu maalu wọn ni ẹbun gba mabinu.