2020 Prophesis: Kí ló mú kí ọ̀pọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ kùnà lọ́dún 2020?

Ó jẹ́ ǹkan tó wọ́pọ́ ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà láti má gbọ àsọtẹ́lẹ̀ ǹkan ti yóò ṣẹ̀lẹ̀ ní ọdún tuntun, ti àwọn ènìyàn yóò si máa retí láti gbọ́ àsọtẹ́lẹ̀ ọdún.

Nítórí ìdí èyí, ọdún 2020 náà kò gbẹ́yìn, bí ọ̀pọ̀ àwọn onígbàgbọ́ ṣe ń fọkàn sí jákèjádo.

Gẹ́gẹ́ bí ìwádìí ṣe fi han, Nàìjíríà jẹ́ ọ̀kan pàtàkì lára àwọn orílẹ̀-è[de tó n ṣe ẹ̀sìn jùlọ, ti awọn ojisẹ Ọlọrun nibẹ si maa n sọ asọtẹlẹ ninu ọdun tuntun.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Onírúurú ní ìṣẹ̀lẹ̀ tó wáye lọ́dún 2020, ti ọdun naa si kún fún ọ̀pọ̀ àinírètí, ikú, òfò ati àdánù,

Kódà ọ̀pọ̀ eeyan ni ìṣẹ́ bọ́ lọ́wọ́ rẹ, èyí kò si ṣẹ̀yìn àjàkálẹ̀ ààrùn Covid-19, àwọ̀n ǹkan ti Covid-19 ṣe yìí mi ìlú tìtì.

Bí gbogbo rẹ̀ ṣe wá rí, ọ̀pọ̀ òjíṣẹ́ Ọlọrun ni kò mọ̀ pé ajakalẹ arun gan yóò ṣẹ̀lẹ̀ lásìkò tí wọn ń kéde àsọtẹ́lẹ̀ ni ibẹrẹ ọdún tuntun.

PasitAdejare Adeboye:

Alákoso àgbà fún ìjọ Redeemed Christian Church of God (RCCG), Pásítọ̀ Enoch Adeboye sọ pé, ilẹ̀ rírì yóò pọ̀ tí "Volcano" náà yoo da àwọn orílẹ̀-èdè láàmú, sùgbọ́n ti ọdún fi pari, irú ìṣẹ̀lẹ̀ yìí kò wọ́pọ̀.

O ní ọdún 2020 yóò dàbi ọmọ tó ni gìrì nítori ilẹ̀ rírì, nítóri ẹ̀sẹ̀ ti pọ̀ jù, àfi ti ọmọ Nàìjíríà bá gbàdúrà gidi.

Ẹ̀wẹ̀, ìròyìn nípa "Volcano", eyiun isẹlẹ ina alagbara to n ran bii ẹtu, ko fi bẹ́ẹ̀ wọ́pọ̀ ni 2020, gẹgẹ bi ojisẹ Ọlọrun naa ti sọ tẹlẹ, ilẹ̀ ríri náà ko sì tó ǹkan.

Pastor T.B Joshua:

Olùdarí ìjọ Synagogue church of All Nation (SCOAN), ni ọ̀pọ̀ eeyan ti bu ẹnu àtẹ́lù nítorí àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ pé inú oṣù kẹta ọdún, 2020 ni ààrun Coronavirus yóò lọ.

Amọ titi di àsìkò yìí, arun náà kò ti fi gbogbo àgbáyé sílẹ̀, ti ọwọja rẹ si n peleke si.

Orin tó gba ilú kan báyìí ni pé, sáà coronavirus míràn tun ti dé, èyí sì ló fáa ti àwọn ìjọba fí n sọ fún ará ìlú láti mase lọ fún ìsìn òpin ọdún.

Chris Oyakhilome:

Olùdásílẹ̀ ìjọ Love World Incorporated ti gbogbo ènìyàn mọ̀ sí Christ Embassy, Chris Oyakhilome kéde pé ọdún àṣepé ni 2020.

Sùgbọ́n ọdun 2020 ko tilẹ̀ súnmọ́ àṣèpé rárá, kò ti pé oṣù mẹ́ta tí ọdún bẹ̀rẹ̀, lọ̀rọ̀ ààrun Coronavirus gbera sọ.

Bákan náà ló sọ àsopọ̀ tó wà láàrín 5G àti Covid-19.

David Oyedepo

Olùdarí ìjọ Living Faith ChurchBísọ́ọ̀bù David Oyedepo náà kò gbẹ́yìn nínú àwọn tó sọ àsọtẹ́lẹ̀ fún ọdún 2020

Nínú àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀, ó ní ọdún 2020 yóò jẹ́ ọdún ti àlùyọ, sùgbọ́n òdi ní èyí bọ́sí nítori ó jẹ́ ọdún tí ọ̀pọ̀ ń súkún.

Williams Kumuyi

Ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún 2020, olùdáílẹ̀ ìjọ Deeper Life Bilble Church, Williams Kumuyi só fún ìjọ rẹ̀ pé, ọdún yìí ni yóò dára jùlọ nínú gbogbo ọdún ti wọ́n ti lò láyé.

Sùgbọ́n ó jọ bí ẹni pé, ọ̀ps ló sọ pé àwọn kò tí lo irú ọdún yiìí rí láti ìgbà ti àwọn ti dáyé.

Wale Olagunju

Ní ti olùdarí ìjọ Divine Seed of God Chapel Ministry Ibadan nípìnlẹ́ Oyo, Wale Olagunjusọ pé , Gómínà ìpińlẹ̀ Kaduna Nasir El-Rufai àti Kayode Fayemi ti ìpínlẹ̀ Ekiti tó fi mọ́ ìdá ààdọ́rin ọmọ ẹgbẹ́ APC ni yóò kúrò nínú ẹgbẹ́ naáà. Eyi kò ti ṣẹ.

Bákan náà ni Olagunju ni kí Ọba ilú oyinbo (Queen Elizabeth) máa ka ọjọ́ rẹ̀ lórí ilẹ̀ èèpẹ̀, Sùgbọ́n títí di àsìkò yìí, koko ni ara i[yá lé, bi ó ṣe bá àwọn ẹbí rẹ̀ ṣe ayẹyẹ ọdún kérésìmesi ni Windsor Castle ni London.

Ó tun sọ pé, ti Obaseki bá kúrò ni inú ẹgbẹ́ míràn, yóò padànú ìbò gómínà ọdún 2020, Obaseki lọ sínú ẹgbẹ́ PDP síbẹ̀ ó jáwé olúborí.

Ó ní Donald yóò wọlé ààrẹ ilẹ̀ Amẹrika yóò jáwé olúborí ni ọdún 2020.

Paul Okikijesu

Woli ìjọ Christ Apostolic Miracle Ministry Paul okikijesu sọ asọtẹlẹ̀ tirẹ̀ ni inú oṣù kọkànlá ọdun 2019 ní bi tó ti sọ pé, àwọn angẹli ti wa ni ìpińlẹ̀ makandinláádọ́rin tí wọ́n yoo si wọ orílẹ̀-è[de ọgọ́fa àti mẹ́rìnlélógún,

Nínú àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ o ni wọ́n yóò wọ ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè ẹ̀ ó sì gba iròyìn pé Ọlọrun n bínu.

Ó ní ìṣẹ̀lẹ̀ ti kò ṣẹ̀ rí yóò ṣẹ̀, "ẹ̀ ó sì gba pé àwọn angẹ́lì gangan ló n ṣe ìdájọ́" Tí èyí kò bá rí bẹ́ẹ̀, ẹ sọ pé Ọlọrun kọ́ ló pè mí"

Títí di àsìkò yìí a kò ti gbọ́ pé àwọn angẹ́lì ń 'se ìdájọ́ níńu ayé.

Bákan náà ni Okikijesu ni Ọlọrun yoo pa àjàkálẹ̀ ààrun Covid-19 rẹ́ nínú oṣù keje ọdún, sùgbọ́n títí di àsìkò yiìí ààrun Covid-19 n gbilẹ si ni.