You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Commonwealth scholarship 2020/2021: Wo ìlànà ìforúkọsílẹ̀ fún ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́ Ph.D àti Fellowship
Ileeeṣẹ eto ẹkọ ni Naijiria, ti fi iwe ipe sita fun gbogbo ẹni to ba nifẹ, to si koju oṣuwọn, lati fi orukọ silẹ fun eto ẹkọ ọfẹ Commonwealth fun ọdun 2020/2021.
Ninu atẹjade kan to fi sita, ileeṣẹ eto ẹkọ ni awọn to fẹ kẹkọọ fun oye imọ ijinlẹ Ph.D nikan ni eto naa wa fun.
Eto ẹkọ ọfẹ yii jẹ ọkan lara ẹjẹ ti orilẹ-ede UK jẹ fun ajọ Commonwealth. Akẹkọọ to to ẹgbẹrin si lo ma n ni anfaani lati kawe fun imọ ijinlẹ keji soke, ni awọn fasiti to wa ni UK.
Bi o ṣe le fi orukọ silẹ
- Gbogbo olukopa gbọdọ lọ si ori ayelujara cscuk.dfid.gov.uk/apply/
- Tẹ bọtinni to ni 'Apply' ni oju ewe akọkọ
- Ka awọn ilana, ki o si sun si isalẹ diẹ lati ṣe akọsilẹ orilẹ-ede rẹ
- Tẹle ilana to wa nibẹ lati fi orukọ silẹ
Ta a lo le kopa?
Lati fi orukọ silẹ fun ẹkọ ọfẹ ajọ Commonwealth, o gbọdọ jẹ ọmọ orilẹ-ede, tabi maa gbe ni orilẹ-ede to wa ninu ajọ yii.
Bakan naa lo le kopa, ti o ba jẹ atipo tabi ọmọ orilẹ-ede Britain.
- Awọn to fẹ gba oye imọ ijinlẹ Ph.D ati Fellowship lo wa fun
- Olukopa gbọdọ ni 1st Class tabi 2nd Class Upper Division, ninu oye imọ ijinlẹ akọkọ
- O gbọdọ ni iwe ẹri NYSC (fun awọn to jẹ ọmọ Naijiria)
- Wọn gbọdọ ti gba olukopa si ile ẹkọ giga ni UK
- Ọ gbọdọ tẹ fọọmu iforukọsilẹ naa jade lẹyin ti o ba ṣe akọsilẹ tan, ki o to tẹ bọtinni 'submit'
- O si gbọdọ ni ẹri pe alamojuto eto ẹkọ rẹ 'supervisor' ni UK fi ọwọ si
- Bakan naa ni o gbọdọ pese ẹri pe o ko ni agbara lati gbọ bukata eto ẹkọ rẹ ni UK, lai si ẹkọ ọfẹ
- Ẹkunrẹrẹ alaye wa ni ojuopo ayelujara CSC
Awọn nkan ti o nilo fun iforuksilẹ
Ki o to bẹrẹ iforukọsilẹ, ṣe ẹda iwe irinna pasipọọti rẹ, akọsilẹ esi idanwo rẹ ni fasiti 'transcript', iwe ẹri to gba ni fasiti, oniduro meji, ati iwe igbaniwọle si fasiti.
Ọpọlọpọ ipele ninu eto ẹkọ ọfẹ yii lo wa pẹlu gbigbọ gbogbo bukata rẹ; owo ileewe, owo baalu lati jade ati pada si UK, ati owo diẹ fun bukata rẹ lasiko ti o ba fi wa nibẹ.
Ọjọ kejidinlogun, oṣu Kinni, ọdun 2021 ni iforukọsilẹ yoo pari, ọfẹ si ni patapata.