Palm Wine drinking: Àǹfààní tí ẹmu ń ṣe fún àgọ́ ara

Gbogbo ilẹ̀ káàrọ̀ -ò-òjííre àti ọ̀ps ibi ni ilẹ̀ Afirika ní àwọn ènìyàn tí máa n rí ẹmu gẹ́gẹ́ bí ǹkan pàtàkì láti fi ṣe àlejò

Èyí nìkàn kọ́, ní ilẹ̀ Igbò, ẹnikẹ́ni tí kò bá fi ẹmu ṣe àlejò yàlá lásìkò àyẹyẹ ìgbéyàwó tàbí ìkómọ jáde kò tíì ṣe ǹkan kan.

Bí wọ́n ṣe máa n sọ bí Igbo bá n sọ̀fọ̀ gan, wọ́n a sì máa mu ẹmu láti rí ìtùnú.

Àǹfàní tó wà nínú Ẹmu mímu

Nítorí ìwádìí yìí, a kàn sí onímọ nípa oúnjẹ àti oun mímu tí ó ṣara láànfàní Harrison Omonhinmin àti Collins Akano láti spalpayé àǹfàní ẹmu ni àga ara.

Collins Akano jẹ́ onímọ̀ nípa oúnjẹ tó ṣara lóore, ó sì sàlàyé pé ẹmu ni àǹfàní fitamin A fitamin B ati C

Ó sàlàyé pé àwọn èròjà yìí maa n ìgbòkè gbodò ara ka dáradára. Bákan náà ni o má n dà bi gírísiì tí gbogbo ríkèé-ríkèé ojú ńlo láti ṣiṣẹ́ ati omi to n ran oju lọ́wọ́ láti ṣẹ́.

Ẹmu mímu kìí jẹ́ kí ènìyàn ní ìtọ̀ súgà

Harrison Omonhinmin ní bótilẹ̀ jẹ́ pé ẹmu ni súgà, síbẹ̀ kìí fún ènìyàn ni ìts súgà bi àwọn ọti míràn ṣe máa n ṣe.

Ẹmu máa ń fun ènìyàn ni okun ati agbára

Omonhinmin tun sàlàyé pe, ẹmu ni èròjà tí à ń pè ni Carbohydrates ni èdè òyìnbó, àwọn èròjà inú ẹmu yìí lágbara gan láti fún ènìyàn lágbáre.

Ó máa n fọ àwọn ìdọ̀tí inú ọkàn mọ́

Akano nínú àlàyé tirẹ̀, ni ẹmu máa n ṣe àtúnṣe ọkan nítorí àwọn èròjà kan tó ni, ó ni ó máa ń jẹ́ kí ọkàn ṣiṣẹ́ dáradára tí ó sì máa n fun ni okun.

Èyí máa n dènà àìsàn ẹ̀jẹ̀ ríru pẹ̀lú.

Akano ni ẹmu fún ara ni Iodine, Zinc àti magnesium láàgọ́ ara

Ẹmu àti àìsàn Jẹjẹrẹ

Akano sàlàyẹ síwájú sí pé, ẹmu ni àwọn èròjà kan tó máa n dènà àìsàn jẹjẹrẹ tó tí n ṣe ẹ̀mí àwọn ènìyàn légbodò tó sí n pa àwọn sẹ́ẹ̀lì ara

Nítorí náà, ẹmu dára púpọ̀ láti dènà ààrùn jẹjẹrẹ

Àpẹrẹ to dara jù ni tí Vitamin B2 to jẹ́ Ribovlavine, èyí maa n ràn ara lọ́wọ́ láti gbógun ti àwọn èròjà tó n Cancer

Se Ọtí máá ń fa Jẹjẹrẹ ọmú

Àwọn ènìyàn ń bèrè ìbérèè nípa ẹmu.

Omonhinmin sọ pé, bótilẹ̀ jẹ́ pe, kò tíi sí ìwádìí ìjìnlẹ̀ lórí bóyá, ọti ń fa jẹjẹrẹ

Kàkà bẹ́ẹ̀ ó ni o sàn fún àwọn aláboyun láti jìnà sí ọtí mímu nítori pé, ọti ni súgà tó pọ̀.

Kíni òdiwọ̀n ọti ti o yẹ ki ènìyàn maa mu ẹmu

Omonhinmin tún fi kun pé ẹmu dara púpọ̀ fún ara, sùgban èyí kò túmọ̀ sí pé kí ènìyàn wá mu ni àmujù

O ní ó dára ki obinrin mu ife kanb lóòjọ́ nígbà ti àwọn ọkùnrin le mu bi ife méjì láàrín ọjọ́ kan.

Njẹ́ ẹmu máa n fa inú rirun tàbi egbò inú (Ulcer)

Collins Akanno ni lóòtọ́ ni ẹmu ni ìdá márun ọti nínú sùgbọ́n kìí fa inú rírun tàbi ẹgbò inú.