Healthy lifestyle: Wo irú ìgbé ayé tó lè mú ẹ̀mí rẹ gùn

Gbigbe igbe aye to dara le fi ọdun mẹwaa kun ọjọ aye awọn obinrin, bakan naa lo le fi ọdun meje kun t'awọn ọkunrin.

Irufẹ bẹẹ tun le dena arun jẹjẹrẹ, arun ọkan ati itọ ṣuga pẹlu awọn arun miran gbogbo.

Iwadii ajọ BMJ lo fidi ọrọ yìi múlẹ.

Ajọ naa ni ṣiṣe ere idaraya ni gbogbo igba, jijẹ ounjẹ aṣaraloore, lai mu siga ṣe pataki.

Apọju ṣuga mu ki eeyan ni arun jẹjẹrẹ.

Ijọba orile-ede Ghana ni bibọ ẹran pẹlu paracetamol iku ni!

Kinni gbigbe igbe aye to dara tumọ sí?

Wọn bi awọn eeyan to ti pe aadọta ọdun pe bawo ni wọn se n ṣe mẹrin ninu nkan marun un yii?

Kinni ibeere ti won lo fun iwadii naa?:

1) Boya wọn ko mu siga ri?

2) Boya wọn n jẹ ounjẹ aṣaraloore?

3) Boya wọn n ṣe iṣẹ aṣekara fun ọgbọn iṣẹju?

Ti ara wọn ko ba ju oṣuwọn BMI 18.5 ati 24.9.

4) Boya awọn obinrin ko mu ọti lile to ju kọọbu kan lọ lọjọ kan, ati bo ya awọn ọkunrin ko mu ju igo bia kan lọ?

Awọn obinrin ti wọn ba ṣe mẹrin ninu marun un yii yoo gbe fún ọdun mẹrinlelọgbọn síi lai larun jẹjẹrẹ, arun ọkan ati itọ ṣuga.

Wọn o fi ọdun mẹwaa gbe ile aye síi ju awọn ti kii ba ṣe awọn nkan ti a ti mẹnu ba lọ.

Fawọn ọkunrin, o tumọ sí pe wọn o gbe ọdun mọkanlelọgbọn lai larun kankan.

Ọdun meje ni afikun ọdun ti wọn yoo lo ju awọn ọkunrin ti wọn ko gbe igbese aye to dara lọ