You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ogun iphone theft: Ọkùnrin kan dèrò ẹ̀wọ̀n lẹ́yìn tó jí ẹ̀rọ ìbáraẹnsọ̀rọ̀ tí iye owó rẹ̀ tó ₦950,000
Ọkunrin ẹni ọdun mejilelogun kan ti ri ẹwọn ọdun mẹrin he lẹyin to jẹbi ẹsun ole jija ni ipinlẹ Ogun.
Wọn fẹsun kan Ihetuge Ifeanyi pe o ji ẹrọ ibaraẹnisọrọ ti iye owo rẹ to N950,000.
Adajọ ile ẹjọ naa, O.L. Oke ni ki ọdaran ọhun lọ fi ẹwọn jura fun ọdun mẹrin gbako lẹyin to jẹwọ pe oun jẹbi ẹsun naa ti wọn kan an.
Ṣugbọn Adajọ ọhun fi kun un pe o lee san owo itanra ti iye rẹ to N150,000 dipo ko lọ fi aṣọ penpe roko Ọba.
Ọkunrin naa di ẹni to n kawọ pọn rojọ niwaju adajọ lẹyin ti wọn fẹsun ole jija, ile fifọ ati igbimọpọ hu iwa ọdaran kan.
Agbofinro to gbe ọrọ naa lọ silẹ ẹjọ, E.O Adaraloye sọ pe Ifeanyi atawọn miran ti wọn ti na papa bora huwa ọdaran naa ni nnkan bi aago mẹta oru ni adugbo Femi Oni, to wa ni opopna Arinko, ni Otta, iyẹn ni ipinlẹ Ogun.
- Èmi kọ́ ló pàṣẹ fún àwọn sọ́jà láti má a pa èèyàn ní Oyigbo - Nyesom Wike
- Banki Nàìjíríà, CBN ṣàlàyé nípa àwọn tó máa rí gbà nínú owó ìrànwọ́ N75b tíjọba gbé kalẹ̀
- Kàyééfì! Tọkọ taya kú lọ́jọ́ kan náà l'Abeokuta lẹ́yìn ìgbéyàwó ọdún méjìléláàdọ́rin 72
- Kíní ọ̀nà àbáyọ sí ìjàmbá ọkọ̀ tó ń wáyé lemọ́lemọ́ ní Ọjà Akungba,ní Ondo?
Adaraloye sọ pe Ifeanyi atawọn ẹmẹwaa rẹ fọ ile ọkunrin kan ti orukọ rẹ n jẹ Olayinka Odunniyi, ti wọn si ji ẹrọ ilewo iPhone atawọn ẹrọ ilewọ olowo gọbọi miran.
O ni iwa ti wọn hu lodi si ofin to rọ mọ iwa ọdaran ipinlẹ Ogun ti wọn gbe kalẹ lọdun 2006.