Rauf Aregbesola sọ bó ṣe yẹ kí òbí máa fètò sọ́mọ bíbí

Minisita to n ri si ọrọ abẹle lorilede Naijiria to tun jẹ gomina ana ipinlẹ Osun, Ọgbẹni Rauf Aregbesola ti ni ki awọn obi din iye ọmọ ti wọn n bi ku.

Aregbesola sọ eyi gẹgẹ bi ọkan lara awọn koko ọrọ to maa n fi sita lori ayelujara.

O fi ọrọ rẹ gba awọn lọkọ-laya nimọran lati fi eto si bi wọn ṣe n bimọ nitori ipo ti orlẹede Naijiria wa lọwọlọwọ.

Loju opo Twitter ti Ọgbẹni Aregbesola maa n lo fi kọ awọn koko ọrọ kekeke, o ni "a rọ awọn lọkọ-laya lati maa feto sọmọ bibi".

O tẹnu mọ ọ pe "a ti n bimọ ju iye awọn ti orilẹede ṣetọju lọ. Torinaa, ọmọ meji si mẹta ti to".

Aregbe ni o yẹ keeyan ṣe bo ṣe mọ ni, ẹlẹwa sapọn lori ọrọ ọmọ bibi lorilẹede Naijiria.

Niwọnba iwọn iye owo tabi na atijẹ ti eeyan ni ni Ọgbẹni Aregbesola ni o yẹ keeyan wo ko to maa ka ọmọ jọ.