U S Election: Aàrẹ Donald Trump kọ̀ láti fí àrídájú síta pé òun yóò gbè ìjọba kalẹ̀ láìsí wàhálà

Aarẹ Trump ṣetan lati yan Amy Coney Barrett sile ẹjọ giga julọ ni America iyẹn 'Supreme Court'

Aarẹ Trump ni iroyin n tan kalẹ pe o fẹ yan Amy Coney Barrett to jẹ ololufẹ awọn ti wọn n tẹle ilana aatẹlẹ atijọ ni America gẹgẹ bii Adajọ nile ẹjọ to ga julọ ni America.

Ko to di ọjọ Aje to m bọ ni iroyin naa ni Aarẹ Trump yoo yan Adajọ amy naa.

Awọn alajọṣiṣẹpọ pẹlu ileeṣẹ BBC ni America, CBS News ati awọn ileeṣẹ iroyin miran ti fidi eyi mulẹ fun BBC.

Amy ni yoo rọpo Adajọ Ruth Bader Ginsburg to ku lọjọ Ẹti.

Iyansipo rẹ yii yoo fẹẹ di wahala nile igbimọ aṣofin ti wọn ba fẹ buwọluu loṣu kọkanla.

Ileeṣẹ iroyin CBS ṣalaye pe Aarẹ ti pinnu lati yan Adajọ Barrett lẹyin ti ọpọlọpọ orisun fidi eyi mulẹ

Ṣugbọn ni alẹ ana ọjọ Ẹti nigba ti wọn beere lọwọ Trump, o ni ẹni ti wọn n gbeyawo wa ba kii garun woo.

Pe laipẹ ni gbogbo agbaye a mọ ẹni ti oun yan sipo naa nitori pe gbogbo Adajọ to tọ si naa lo jẹ akọsṣẹmọṣẹ.

Aarẹ Trump ni ilẹ ẹjọ giga lo ṣeeṣe lati yanju ọrọ idibo to wa nilẹ yii ni eyi ti ile ẹjọ giga America ni lati ni Adajọ mẹsan an lasiko yii ki ohun gbogbo le yanju.

Trump kò ní gbé ìjọba sílẹ̀ pẹ̀lú ìrọ̀rùn tí kò bá wọlé padà

Aarẹ Donald Trump kọ̀ lati fẹnu ọrọ jona lori boya oun maa gbe ijọba ijọba silẹ pẹlu irọrun tabi bẹẹ kọ lẹyin idibo.

O ni oun yoo maa wo ohun ti yoo ṣẹlẹ lasiko idibo ati lẹyin idibo.

Aarẹ Trump sọ eyi nibi ipade awọn akọroyin nile ijọba ni White House ni America.

O ni oun gbagbọ pe o ṣeeṣe ki wọn gbe esi idibo naa gba ile ẹjọ to ga julọ lẹyin idibo ọhun.

Ọpọlọpọ ipinlẹ lo n faramọ eto idibo alapo iwe fifiranṣẹ nitori itankalẹ arun ccoronavirus.

Ṣaaju ninu itan ilẹ America ni awọn oludije ti maa n gba esi idibo to ba jade bo ba ṣe ri.

Ti aarẹ Donald Trump ba kọ lati gba esi idibo naa yoo fa itẹsiwaju iṣejọba alagbada ni America sẹyin.

Ṣaaju ni Joe Biden to jẹ oludije lẹgbẹ oselu Democrat to n koju Trump to jade labẹ ẹgbẹ Republican ti ni awọn ọmọ ogun ni yoo wa le Trump kuro nile ijọba lẹyin idibo to ba kọ lati kuro.

Trump ni awọn iwe idibo ati ọna rẹ ko tẹ oun lọrun, o ni ifẹhonuhan yoo dẹkun ni kete ti wọn ba ti palẹmọ awọn apoti idibo ti wọn n lo bayii.