Coronavirus Updates: Àì gba ìwé àṣẹ ìjọba ṣàkóbá fún sinima orítá ọmọkùnrin yìí
Ẹgbẹlẹgbe owo ni Arakunrin Rotimi Ojo-Abegunde fi ṣofo lasiko to se eto sinima fun awọn eniyan lati wa wo ninu ọkọ wọn.
Abegunde ni oun gbero pe ki awọn eniyan le ri sinima wo lasiko ajakalẹ arun Coronavirus yii, ti ipinlẹ Eko si ti gba ki awọn eniyan ma a jade lo si ibi ise.
O ni iye owo ti oun na si ori sinima naa le ni ẹgberun lọna ẹgbẹta naira, ti awọn ero si pe jọ si bẹ, ki ijọba to wa le wọn danu.
Amọ, ijọba ipinlẹ Eko ni ọrọ ko ri bẹ ẹ, wọn gbọdọ gba iwe aṣẹ lọwọ ijọba wi pe ohun ti wọn fẹ ṣẹ ko tapa si ofin ijọba.
Amọ awọn ero to wa sibẹ sọ wi pe ijọba ko se daato nitori wọn gbegidi sinima awọn.