Coronavirus: Báyìí ni àwọn sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀ lórí rédíò ní Rwanda ṣe ń pín ìròyìn nípa ìmọ́tọ́tọ́ araẹni

Awọn eeyan kan lorilẹ-ede Rwanda ti bẹrẹ si n ṣe ere ori redio lati kọ awọn olugbọ wọn nipa ṣiṣẹ imọtoto araẹni lasiko ajakalẹ arun Coronavirus.

Awọn ere ọhun ni wọn n ṣẹ pẹlu ajọṣẹpọ ajọ kan ti kii ṣe ti ijọba, ti orukẹ rẹ n jẹ "WaterAid" fun ọdun kan ati abọ.

Ayaworan kan, Elena Heatherwick lo n kọ itan naa, ti ileesẹ igbohunsafẹfẹ si ma fi sita fun eti igbọ awọn eeyan.

Ilẹ Rwanda lo kọkọ kede ofin konile-o-gbele nilẹ Afrika lẹyin ti arun ọhun rapala wọn orilẹ-ede naa lọjọ kejilelogun, oṣu kẹta ọdun 2020.

Awọn onwoye ọrọ to n lọ ti sọ pe ere ori redio ọhun n ko ipa to pọ ninu didẹkun arun naa nilẹ ọhun.

Redio jẹ ọna kan gboogi lati ṣe ikede lorilẹ-ede Rwanda niwọn igba ti eeyan kan ninu mẹrin ko lee kawe nilẹ ọhun.

Ere naa ma n de ọdọ miliọnu mrin eeyan o kere tan, eyi to jẹ ida mẹta awọn eeyan to wea lorilẹ-ede ọhun.