You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
#BuhariChallenge: Kí ló m'àwọn èèyàn máa fi àwòrán s'ọko ọrọ sí ààrẹ Buhari lórí Twitter?
Bi eeyan ba ṣere lọ si oju opo Twitter ni Ọjọ Ẹti ta wa yi ni Naijiria, yoo ṣoro ki o to ma ṣe alabapade ọrọ to n ja rain labẹ akori #BuhariChallenge.
Ki lohun to ṣokunfa akori yi ati pe ki gaan lawọn eeyan n gbero pẹlu rẹ?
A ko le sọ ni pato ohun tonikaluku ni lọkan ṣugbọn ni afojusun nkan to n ṣẹlẹ ni Naijiria bayi, ko ṣẹ lẹyin bi awọn ọmọ Naijiria ti ṣe n figbe ta ki aarẹ Buhari ba awọn eeyan ilẹ naa sọrọ nipa arun Coronavirus.
Ki a to ṣe atupalẹ ọrọ yi, ẹ jẹ ki a tiẹ yẹ diẹ wo ninu awọn aworan ti awọn eeyan n ṣalabapin ati akọle ti wọn fun wọn
Ọrọ ti ọgbẹni Joseph D.Clean sọ ni akori si aworna tirẹ ni pe Ọba obinrin ilẹ Gẹẹsi ṣe abẹwo si aarẹ Buhari lati sọrọ nipa iwọlepada idije Premiership.
Akinsanya Owolabi ni tirẹ sọ pe aarẹ Amerika ana Barak Obama ati awọn olori miran ti fọwọ si pe ki wọn wa aarẹ Buhari jade.
Awọn aworan miran ree pẹlu akọle wọn ti fi han pe awọn ọmọ Naijiria n reti ki aarẹ Buhari jade sọrọ lori Coronavirus
Kini ileeṣẹ Aarẹ n sọ?
Loju opo Twitter ileeṣẹ aarẹ Naijiria, wọn fi ikede sita pe ki awọn eeyan ma ṣe ka fọnran kan nipa ibi ti aarẹ wa kun.
Idi ni pe iroyin ẹlẹjẹ ni. Siwaju, ileeṣẹ aarẹ fi aworan aarẹ han nibi ti o ti n ṣiṣẹ ni ọfisi rẹ
Ni afikun, Femi Adesina to jẹ oluranlọwọ agba si aarẹ Buhari lori ibaraẹnisọrọ lori eto ileeṣẹ amounmaworan kan nilẹeṣẹ Channels TV da si ọrọ yi.
Adesina ni aarẹ Buhari ko fẹran lati ma sọrọ nipa ohun to ba n ṣẹlẹ. Gẹgẹ bi o ti ṣe sọ, adamọ aarẹ yatọ si tawọn aarẹ mi nitorinaa ko di dandan ko ba awọn ọmọ Naijiria sọrọ.