í ammy awards: Davido, àwọn ọmọ ṣe àdúrà fún Burna boy lórí àmì ẹ̀yẹ Grammy

Oríṣun àwòrán, other
Ayẹyẹ eto ami ẹyẹ orin lagbaye, Grammy yoo waye laṣalẹ oni, oju ọpọ ọmọ Naijiria ni yoo si wa lori ayẹyẹ naa.
Ko si idi meji fun eyi ju pe, lasiko ti ayẹyẹ ami ẹyẹ ọhun ba n waye, gbajugbaja akọrin ọmọ Naijiria kan Damini Ogulu ti ọpọ mọ si Burna boy yoo maa wa lara awọn ti orin wọn yoo wa nikalẹ fun yiyan flati gba ami ẹyẹ.
Awo orin Burna Boy to pe akọle rẹ ni 'African Giant'wa lara awọn orin ti wọn yan fun ami ẹyẹ orin to dara ju lati awọn orilẹede miran lagbaye, World Music Album.
Eekan akọrin takasufe lorilẹede Naijiria, Davido ti fi adura ranṣẹ si Burna boy pe agere rẹ yoo ri ẹja mu nibi ayẹyẹ ami ẹyẹ Grammy tọdun yii.
Loju opo Twitter rẹ, Davido ni oun ti ri orukọ Burna boy lori ami ẹyẹ naa, ko maa dupẹ, ko maa yọ.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post
Ayẹyẹ ami ẹyẹ grammy ti ọdun yii ni yoo jẹ ẹlẹkejilelọgọta rẹ ti yoo maa waye.
Ọpọ ireti ni awọn ọmọ orilẹede Naijiria ni lori pe Burna boy yoo le da igbo ami ẹyẹ naa lu fun awọn akọrin orilẹede Naijiria.
Kii ṣe Burna boy ni akọrin akọkọ lati orilẹede Naijiria ti orukọ rẹ yoo jade lori iwe orukọ awsn ti wọn yoo dibo mu fun ami ẹyẹ nibi eto Ami ẹyẹ Grammy.
Awọn olorin bii King Sunny Ade, Femi Kuti naa ti wa nirufẹ ipo bẹẹ ri bi o tilẹ jẹ pe wọn ko rii gba.













