Mali Attack: Ọmọ ogun ilẹ̀ mẹ́tàléláàdọ́ta ni wọ́n ti pa nínú ìkọlù Mali

Awọn agbebọn ni orilẹ-ede Mali ti ṣe iku pa awọn ọmọ ogun ilẹ Mali mẹtalelaadọta ninu ikọlu to waye nibudo awọn ọmọ ogun ni ariwa Mali.

Ileeṣẹ awọn ọmọ ogun ilẹ Mali ti fi atẹjade sita ni eyi ti wọn fi ṣapejuwe awọn agbebọn yii ni agbesunmọmi ti wọn kọlu ọmọ ogun.

Wọn ni eyi jẹ ikọlu to buru julọ laarin ọdun mẹwaa sẹyin nitori ẹmi ara ilu kan naa ba iṣẹlẹ yii rin.

Lati ọdun 2012 ni irufẹ ikọlu bayii ti n ṣẹlẹ ni orilẹ-ede Mali lati igba ti awọn to n jagun Jihad ti gba ariwa Mali patapata.

Lọjọ Ẹti lo waye ni agbegbe Indelimane ni ẹkun Menaka nila oorun ariwa orilẹ-ede Mali.

Mali ti n gbiyanju lati gba ẹkun yii pada lọwọ awọn oniṣẹ ibi naa ni eyi ti awọn ọmọ ogun ilẹ Faranse ti n ran wọn lọwọ lati gba pada.

Bayii, irufẹ ikọlu yii ti n ṣẹlẹ ni awọn ẹkun miran ni orilẹ-ede Mali.

Ijọba Mali ni awọn ko tii le sọ ni pato boya Ansarul Islam to ṣe ikọlu to ṣaaju naa lo tun wa nidi eyi tabi bẹẹkọ.

Yaya Sangare to jẹ agbẹnusọ fun ijọba Mali ni awọn ikọlu yi ṣe ọpọlọpọ ninu awọn ọmọ ogun to wa pese iranlọwọ fun wọn nibudo omo ogun leṣe.

O ni awọn mẹwaa ni wọn ṣeleṣe pupọ julọ ninu ikọlu ọjọ Ẹti yii ni eyi to ba ibudo naa jẹ pupọ.

O ni ijọba ti bẹrẹ iwadii ati dida oku awọn to ba ikọlu naa lọ mọ.

Ni ipari oṣu kẹsan an yii ni wọn pa ọmọ ogun mejidinlogoji nigba ti wọn kọlu ibudo awọn ọmọ ogun meji nitosi ẹnu bode Burkina Faso.

Orilẹ-ede Mali, Chad, Niger ati Mauritania wa lara orilẹ-ede G5 Sahel ti awọn ilẹ Faranse n ba ja ogun iṣoro eto aabo.

Orilẹ-ede maraarun ni ikọlu oṣu kẹsan an ko ṣẹyin awọn alakatakiti ẹsin Islam ti wọn n jẹ Ansarul Islam.

Lọdun 2016 ni ajagun jihad Ibrahim Malam Dicko da Ansarul Islam silẹ.