You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Samuel Okwaraji: Ó pé ọdún mọ́kànlélọ́gbọ̀n tí Samuel Okwaraji ṣubú lójú ìjà
Awaye ma lọ kan ko si, ọrun nikan lare mọbọ. O pe ọdun mọkanlelọgbọn lonii ọjọ kejila oṣu kẹjọ ọdun 2020 ti gbajugbaja agbabọọlu orilẹede Naijiria Samuel Sochukwuma Okwaraji ṣubu loju ija.
Ṣe wọn ni iku ogun nii pa akinkanju, iku odo nii pa omuwẹ, oju ija, iyẹn lori papa ni Samuel Okwaraji ku si ninu ifẹsẹwọnsẹ fun ati kopa ninu idije ife ẹyẹ agbaye ti yoo waye ni ọdun 1990.
Ifẹsẹwọnsẹ naa waye ni ọjọ kejila oṣu kẹjọ ọdun 1989 pẹlu orilẹede Angola ni papa iṣere to wa ni Surulere niluu Eko.
- Ohun gbogbo tí mò ń rí ní ààfin tẹ́ mi lọ́rùn, èmí ní mo ní ayé mi- Olori Aanu
- Àwọn ǹkan tí ó yẹ kí o mọ̀ nípa 'Sharia Law' ní Nàìjíríà
- Ọwọ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Kebbi tẹ bàbá àti ìyàwó rẹ̀ méjì fún pé wọn so ọmọ pọ̀ mọ́ ewúrẹ́ fún ọdún méjì
- Diezani gan an ní Hushmummy tó ń bú àwọn Yahoo boys- Àwọn Ọmọ Naijiria lórí Twitter
- Nítorí pé mo gba ẹ̀há kò ní kí ń ṣọlẹ̀ tàbí ṣagbe- Ẹ̀lẹ́hàá Amina
- Èdè Yorùbá dùn lẹ́nu àwọn ọmọ òyìnbó yìí ní Michigan!
Ti o ba wa laye ni, Okwaraji ko ba ti pe ọmọ ọdun mẹrinlọgọta lati ọjọ kọkandinlogun, oṣu karun ọdun 2020 yii.
Ọpọ ọmọ Naijiria papaajulọ awọn ololufẹ ere bọọlu afẹsẹgba lo n ṣe iranti ẹni 're to lọ lori ayelujara.
Ajọ to n ri si ere bọọlu afẹsẹgba ni Naijiria, NFF naa ko gbẹyin, niṣe ni NFF gboṣuba rabandẹ fun ẹni ire to lọ.
Ajọ ni ohun ko le gbagbe ipa ribiribi ti Okwaraji ko ninu ere bọọlu ni Naijiria.
NFF ni titi lai loun yoo maa ṣe iranti akọni agbabọọlu to re iwalẹ asa.
Ǹjẹ́ o tilẹ̀ mọ Samuel Okwaraji, agbábọ́ọ̀lù Nàìjíríà tó 'ṣubú lójú ìjà?
Odu agbabọọlu orilẹede Naijiria ni Samuel Sochukwuma Okwaraji jẹ ni igba aye rẹ, o si ṣoju orilẹede Naijiria fun ọpọ ifẹsẹwọnsẹ. Agbẹjọro to kawe gboye ni o si tun ni iwe ẹri imọ ijinlẹ keji ninu imọ ofin ajọṣepọ ilẹ okeeere, (Masters in International Law)
Ọjọ kọkandinlogun, oṣu karun ọdun 1964, ni wọn bi Sam Okwaraji ni ilu Orlu ni ipinlẹ Imo, o si gba bọọlu jẹun lawọn ẹgbẹ agbabọọẹu to lorukọ ni ilẹ Yuroopu bi AS Roma (1984-1985), NK Dinamo Zagreb (1985-1986), Austria Klagenfurt (1986-1987), VfB Stuttgart (1987-1989) ati SSV Ulm 1846 (loan) (1987-1988)
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Ni ọdun 1988 ni Samuel Okwaraji kọkọ gba bọọlu fun orilẹede Naijiria ninu idije ife ẹyẹ Afrika ninu eyi ti o ti gba ọkan lara awọn goolu to yara wọle ju lọ ninu itan idije naa.
Ka ni Okwaraji ko ku ni, oni yii, ni ko ba pe ọmọ ọdun marundinlọgọta lori oke erupẹ.