Europa League: Arsenal fi Valencia ṣe àtẹ̀gùn wọ àṣekágbá

Valencia Vs Arsenal

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Valencia ló kọ́kọ́ gbá bọ́ọ̀lù sáwọ̀n

Gbogbo ẹni to ba wo ifẹsẹwọnsẹ to waye laarin ikọ agbabọọlu Arsenal ati Valencia l'Ọjọbọ ni yoo gba pe àwọn mejeeji lo mura giri.

Eyi ko ruju rara, ni bo ṣe jẹ pe ni laatrin iṣẹju mọkanla ti ifẹsẹwọnsẹ naa bẹrẹ ni Kevin Gameiro ti gba bọọlu sawọn Arsenal, lati fun Valencia ni ayo akọkọ.Lasiko yii ni àwọn agbabọọlu Arsenal naa ti pakiti mọlẹ, ti Pierre-Emerick Aubameyang si da ayo kan pada fun Valencia laarin iṣẹju mẹtadinlogun ti idije ọhun bẹrẹ.

Pierre-Emerick Aubameyang

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Pierre-Emerick Aubameyang ló gbá àmì ayò méjì nínú mẹ́ta ti Arsenal fi bori

Lasiko yii ni àwọn agbabọọlu Arsenal naa ti pakiti mọlẹ, ti Pierre-Emerick Aubameyang si da ayo kan pada fun Valencia laarin iṣẹju mẹtadinlogun ti idije ọhun bẹrẹ.

Ni ko pẹ ti abala keji idije naa gbera sọ ni Alexandre Lacazette tun fọbale goolu Arsenal , ti Aubameyang si tun gba goolu meji miiran wọle , lati sọ ami ayo Arsenal di mẹrin.

Kevin Gameiro ti Valencia tun gbiyanju lẹẹkan sii to si fun ikọ rẹ ni ami ayo miiran.