Food Measurement: Wo oríṣiríṣi ọ̀nà tí ò lè fi wọn oùnjẹ́ bó bá rú ọ lójú

Àkọlé fídíò, Bí o ṣe lè fí òǹkà, ọ̀mọ̀ ìka tàbí ìkúùkù wọn oúnjẹ́

Onikaluku lo ni ọ̀na ti wọn n gba fi wọn ounjẹ ti wọn ba fẹ se.

Ọpọlọpọ ri i pe iwọn ṣe pataki ninu ounjẹ sise yala ko ma di wi pe ounjẹ ko to tabi o pọ ju.

Ni ilẹ Yoruba, oriṣiriṣi nkan ni wọn fi n wọn ounjẹ latori ọwọ, abọ, agolo, ọ̀rá ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Ẹwẹ, bo ti ri ni ile ẹni kan, ko ri bẹẹ ni dandan ni ile ẹlomiiran; ṣugbọn fun ẹni ti ko tilẹ ni aáyan ati maa wọn ounjẹ ko to se e tabi to nilo iranwọ, oniruuru iwọn lo wa lode.