Election Update 2019: APC ṣèpàdé oníròyìn lAbuja láti dúpẹ́ lọ́wọ́ Nàìjíríà

Alaga ẹgbẹ oṣelu APC, Adams Oshiomole dẹnu ọrọ kọ oludije ẹgbẹ oṣelu PDP, Atiku Abubakar loniruuru ọna ti oun naa gba yọ si ẹgbẹ APC.

Ọpọlọpọ ọrọ lo ti n jẹ jade laarin ẹgbẹ oṣelu APC to wa lori alefa ati ẹgẹ alatako, PDP lati igba ti esi idibo aarẹ Naijiria ti jade.

Alaga ẹgbẹ oṣelu APC, Adams Oshiomole lo ṣide ipade oniroyin naa nilu Abuja pẹlu idupẹ lọwọ gbogbo ọmọ Naijiria.

Oshiomole ni nibayii ti aarẹ Buhari ti wọle gẹgẹ bi aarẹ, o gbudọ ṣe ohun to tọ lati wadii awọn to wa nidi ipaniyan to waye lasiko idibo tori ko si ọmọ Naijiria to yẹ ko ku nitori idibo kankan.

O ni ohun to ṣẹlẹ ti awọn eniyan ri gẹgẹ bi abajade idibo aarẹ jẹ ifigagbaga laarin ọkunrin olootọ kan ati ọkunrin kan ti eeyan le ṣiyemeji lori ootọ rẹ.

"Iya to tọ si Atiku gaan lo jẹ, fẹ lasan lasan ni pe o ni oun kọ abajade esi idibo aarẹ ti ajọ INEC gbe jade".

Oshiomole jẹ ko di mimọ pe awọn gan ti kọ iwe ipẹjọ ranṣẹ si ajọ eleto idibo lati wa ṣalaye bi wọn ṣe ṣeru lori ibo awọn ni ipinlẹ Akwa Ibom. O ni ewo wa ni ti ẹgbẹ alatako to tun kun lori esi idibo Akwa Ibom.

O tun tẹnu m awọn iṣlẹ eru ibo mii ti ẹgbẹ oṣelu APC ati PDP

"Ni nkan to jẹ wi pe awọn adari ajọ eleto idibo kan lawọn ipinlẹ kọọkan n ṣiṣẹ fun ẹgb oṣelu PDP lodi si APC ni"

O tẹnu mọ ọ pe gbogbo ero Atiku ni pe idibo ko waye ni irwọ irsẹ̀ ti kii ba ṣe oun lo wọle gẹgẹ bi aarẹ.

Bi o til jẹ pe wn gba pe kudiẹ kudiẹ waye lawọn ipinlẹ kan, o ni Atiku kan n gbiyanju lati tabuku ba idibo to waye ni irọwọ irọsẹ ni plu gbogbo ọr to n ran ẹnu mọ.

Ṣugbọn o ni ki awọn ọmọ Naijiria ma foya tori awọn ko wẹwu ogun, ajọyọ ijọba awa ara wa lawọn yan laayo.