You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
OsunElectionUpdates2018: Ọ̀rọ̀ bẹ́yìn yọ fún PDP lórí ìbò ibùdó méje
Àjọ INEC kéde pé Alhaji Gboyega Oyetola ti ẹgbẹ oṣelu APC ló jáwe olúborí nínú idibò Ọṣun.
INEC ni APC ni ìbò 255, 505 nigba ti PDP ni ìbò 255, 023, eyi to fihan pé Alhaji Oyetola bori Senato Ademọla Adeleke ti ẹgbẹ oṣelu PDP ti wọn jọ na atundi ìbò toni tan bi owó ati awọn oludije to ku.
Iyatọ ibo laarin awọn oludije mejeeji ni 482.
Ọjọgbọn Fiwapẹ to ṣe ikede naa ni eto idibo ọhun ri bi oun ṣe kaa fun ẹgbẹ osẹlu kọọkan àti oludije wọn.
Lọjọ kejilelogun, oṣu kẹsan an, ọdun yii ni idibo naa waye nibi ti ẹgbẹ oṣelu PDP ti ni 254, 698 nigba ti APC ni 254, 345. SDP ni 128,049 nigba ti ADP ni 49 744, ti ADC 7 681.
353 ni odiwọn iye ìbo ti PDP fi ju APC lọ nigba ti ìbò 3, 498 ni wọn wọgile eyi ti wọn ṣe atundi rẹ loni.
Oludije mejidinlaadota lo dije du ipo gomina ipinlẹ Ọṣun lọdun 2018.
INEC ni oun kò kede ẹnikẹni gẹgẹ bi ẹni to jawe olubori nitori ibo ti wọn fagile ni ibudo meje ti wọn ti ni ki atundi ìbò waye loni pọ ju iye ti PDP fi ju APC lọ.
Awọn ibudo idibo ti atundi ti waye loni ni Ifẹ North wọọdu 10; Ifẹ South Olode wọọdu 7; Ifẹ South Osi wọọdu 8; Orolu wọọdu 8 ibudo 001; Orolu wọọdu 8 ibudo 004, àti Osogbo Ataoja wọọdu 5.
Eyi tumọ si pe Alhaji Gboyega Oyetọla ti APC lo maa tukọ ipinlẹ Ọṣun gẹgẹ bii gomina tuntun fun ọdun mẹrin to m bọ.
Kíni òdiwọ̀n iye ìbò ìpínlẹ́ Ọṣun?
Ọjọgbọn Adeọla Fiwapẹ to jẹ alakoso ètò ìdìbò naa ṣalaye pé, gbogbo ìbò yẹ kó jẹ́ 1, 678, 985.
O ni odiwọn iye àwọn oludibo to forukọ silẹ jẹ 775, 675.
Fiwapẹ ni àwọn ojulowo ibo ti wọn dì jẹ́ 721, 621.
Nigba ti gbogbo ibo ti wọn fagile jẹ́ 47, 874. apapọ gbogbo r jẹ́ 769, 495.