Ilé ẹjọ́ fún Sẹ́nétọ̀ Adeleke lọ́jọ́ mẹ́rin láti pèsè ìwé ẹ̀rí Fásitì

Oríṣun àwòrán, Ademola Adeleke/Facebook
Ilé ẹjọ́ gíga ti ìpínlẹ̀ Ọṣun ti ké sí olùdíje fún ipò Gomìnà ni ẹgbẹ́ òṣèlú PDP tó tún jẹ́ Sẹ́nétọ̀ báyìí nílé ìgbìmọ̀ aṣòfinláti wá fi ìwé ẹ̀rí rẹ̀ hàn.
Ademọla Nurudeen Adeleke tó ń ṣojú ẹkùn ìdìbò Ìwọ̀ Oòrùn ìpínlẹ̀ Ọṣun ni wọ́n fi ẹ̀sùn kàn wí pé kò kẹ́kọ̀ọ́ jáde ní Fásitì Jacksonville State University(JSU).
Àwọn aláṣẹ ilé ìwé gíga Fásitì náà tó wà ní Jacksonville ní Alabama, United States ló sọ ọ̀rọ̀ yìí.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ sí:
Nínú àkọsílẹ̀ nípa Sẹ́nétọ̀ yìí tó wà lórí ìkànì ayélujára ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin àgbà, Adeleke ní oyè Diploma nínú imọ̀ ẹ̀kọ́ nípa ọ̀daràn ó sì kẹ́kọ̀ọ́ jáde ní ọdún 1986.
Ó tú kẹ́kọ̀ọ́ jáde ní ilé ìwé girama Ẹdẹ Muslim Grammar School lỌ́ṣun pẹ̀lú ìwé ẹ̀rí Ordinary Level Certificate.
Ẹ̀wẹ̀, wọ́n ti pe àwọn ìwé ẹ̀rí tó sọ pé òun ní níjà. Nínú èyí, ó hànde wípé Adeleke forúkọ sílẹ̀ fún ìdánwò GCE C'O'Level lọ́dún 1981 sùgbọ́n ó fìdí rẹmi nínú èdè Gẹ́ẹ̀sì tí wọ́n sì kàá sí pé kò fara hàn nínú àwọn ìdánwò tó kù.
Ní ìdàkejì, Dele Adeleke tó jẹ́ àbúrò Ademọ̀la Adeleke bu ẹnu àtẹ lu ẹ̀sùn náà ó sì gba àwọn tó kọ̀ láti wá àrídájú ìwé ẹ̀rí Sẹ́nétọ̀ náà níyànjú wí pé "ṣé ẹ rò wí pé ẹgbẹ́ òṣèlú APC kò ti ní gbé ọ̀rọ̀ náà síta bí kò bá ní àwọn ìwé ẹ̀rí tó dájú?













