Ọmọ ọdún 8 fi ọdún kan àbọ̀ ka ilé ìwé Girama

Ọmọ ọdún 8 wọ ilé ìwé gíga Yunifásitì

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Ọmọ ọdún 8 wọ ilé ìwé gíga Yunifásitì

Ọmọkùnrin orílẹ̀èdè Belgium kan tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́jọ kẹ́kọ̀ọ́ jáde ilé ìwé girama lẹ́yìn tó fi ọdún kan àbọ̀ péré kẹ́kọ̀ọ́ ọlọ́dún mẹ́fà.

Gẹ́gẹ́ bí àwọn òbí rẹ̀ ṣe sọ ọ́, Laurent Simons, ẹni tí bàbá rẹ̀ jẹ́ ọmọ orílẹ̀èdè Belgium tí ìya rẹ̀ sì jẹ́ oní èdè Dutch ní ọpọlọ tó pé kọjá àfẹnusọ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ sí:

Àkọlé fídíò, Àyàn: Ti mo bá ti gbọ́ ohùn ìlù ni àárẹ́ mi ma ń lọ!

Ọmọ ọdún mẹ́jọ̀ náà gba oyè Diploma pẹ̀lú àwọn ọmọ ọdún méjìdínlógún ní kílààsì kan náà.

Nígbà tó ń bá ilé iṣẹ́ Rẹ́díò Belgium sọ̀rọ̀, Laurent ní ìsirò ni ẹ̀kọ́ tóùn fẹ́ràn jú nítoríi bó se fẹ̀, ṣíṣe àròpọ̀, ẹ̀ka geometry àti algebra.

Ìròyìn tó ni létí wí pé lẹ́yìn ìsinmi oṣù méjì, yóò bẹ̀rẹ̀ fásitì.

Bàbá rẹ̀ ní ọmọ òun ti tiraka nígbà tó kéré sí àwọn ọmọ míì tó máa ń fẹ́ bá ṣeré bẹ́ẹ̀ sì ni kìí sábà fẹ́ràn ǹkanìseré ọmọdé ṣeré.

Ó ní dókítà níṣẹ́ abẹ ni ọmọ òun fẹ́ dì tàbí a'sèwádìí inú afẹ́fẹ́ sùgbọ́n ní báyìí', ó tún rò ó láti dáwọ́lé iṣẹ́ ẹ̀rọ ayárabíàṣá.

"Bí ó bá sì d'ọ̀la tó ní iṣẹ́ kápẹ́ntà ló wu òun, kò lè jẹ́ ìṣòro fún wa, níwọ̀n ìgbà tí iú rẹ̀ bá ti dùn," ni bàbá rẹ̀ sọ.