You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
#EndSARS: Pe nọ́mbà wọ̀nyìí láti fẹjọ́ ọlọ́pàá SARS sùn
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 1
Awọn ọlọpaa Naijiria ti kede awọn nọmba ti awọn eeyan le pe wọn sori ẹ ti awọn ọlọpaa SARS ba n dunkooko mọ wọn
Iṣẹ awọn ọlọpaa SARS ni lati gbogun ti iwa ibajẹ lawujọ paapa julọ lati daabo bo awọn ara ilu lọwọ awọn adigunjale.
Ṣugbọn ọgọọrọ eeyan lo ti n kerora pe awọn ọlọpaa SARs n fi ẹtọ wọn dun wọn.
Eyi lo jẹ ki ile iṣẹ ọlọpaa orilẹ-ede Naijiria kede awọn nọmba ti ẹnikẹni le pe wọn si ti wọn ba ni ẹsun ti wọn fẹ fi kan ọlọpaa SARS.
Awọn eeyan le lo nọmba yii lori oju opo whatsapp tabi atẹjiṣẹ
Koda awọn to ba ni ẹsun lati fi kan ọlọpaa ti ki i ṣe SARS naa lanfani lati pe awọn nọmba yii.