You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Kayọde Ajulọ; Bílé aṣòfin ṣe pe igbá rẹ̀; ni wọ́n ṣe pè é
Laarin ọsẹ meji, ile asofin ti pe Ọga agba ile-isẹ ọlọpaa lati wa rọ ẹjọ lori isekupani to n sẹlẹ ni Benue ati ọrọ to ni ise pẹlu panpẹ ọba ti wọn fi mu asofin, Dino Melaye.
Amọ, Amofin Agba kan lorilẹede Naijiria, Kayode Ajulo ni ofin to de ile-isẹ ọlọpaa ti Naijiria, sọ wi pe ko pọn dandan fun ọga ọlọpa o yoju si ile asofin lẹyin ti o ti ran igbakeji rẹ lati soju rẹ.
Ajulọ ni ile asofin agba ti da oselu pọ mọ ofin ile Naijiria nitoripe igba ti wọn ba fẹ se abadofin kan ni wọn ni anfaani lati pe ẹnikeni lati wa sọrọ ni ile asofin naa labẹ ofin.O parọwa si awọn asofin naa, lati tẹle ofin ti o de ẹka asofin ilẹ Naijiria, ki wọn ma ba a ni ijakulẹ nigbakigba ti wọn ba ranṣẹ si ẹnikeni lati wa si ile igbimọ asofin naa.
Ti a ko ba gbagbe, ọpọlọpọ igba ni awọn aṣofin ti kọ̀wé si awọn eniyan lati wa si ile asofin ti wọn ko si ni yọju, lara wọn ni Ọga agba aṣọbode orilẹ-ede Naijiria, ajagunfẹhinti Hameed Ali, to kọ̀ lati yọju si ile asofin lọdun to kọja.